Isa 46 YCE

1 BELI tẹriba, Nebo bẹrẹ̀, oriṣa wọn wà lẹhin awọn ẹranko, ati lẹhin ohun-ọ̀sin; a di ẹrù wiwo rù nyin; ẹrù fun awọn ẹranko ti ãrẹ̀ mu.

2 Nwọn bẹ̀rẹ, nwọn jumọ tẹriba; nwọn kò le gbà ẹrù na silẹ, ṣugbọn awọn tikala wọn lọ si igbèkun.

3 Gbọ́ ti emi, iwọ ile Jakobu, ati gbogbo iyoku ile Israeli, ti mo ti gbe lati inu wá, ti mo ti rù lati inu iyá wá.

4 Ani titi de ogbó emi na ni; ani titi de ewú li emi o rù nyin; emi ti ṣe e, emi o si gbe, nitõtọ emi o rù, emi o si gbàla.

5 Tani ẹnyin o fi mi we, ti yio si ba mi dọgba, ti ẹ o si fi mi jọ, ki awa le jẹ ọ̀gba?

6 Nwọn da wura lati inu apò wá, nwọn si fi iwọ̀n wọ̀n fadaka, nwọn bẹ̀ alagbẹdẹ wura, o si fi i ṣe oriṣa: nwọn tẹriba, nwọn si nsìn.

7 Nwọn gbe e le ejika, nwọn rù u, nwọn si fi i sipò rẹ̀; o si duro: ki yio kuro ni ipò rẹ̀; nitõtọ, ẹnikan yio kọ si i, ṣugbọn ki yio dahùn: bẹ̃ni ki yio gbà a kuro ninu wahala rẹ̀.

8 Ẹ ranti eyi, ẹ si fi ara nyin hàn bi ọkunrin: ẹ gbà a si ọkàn, ẹnyin alarekọja.

9 Ẹ ranti nkan iṣaju atijọ: nitori emi li Ọlọrun, ko si si ẹlomiran, emi li Ọlọrun, ko si si ẹniti o dabi emi.

10 Ẹniti nsọ opin lati ipilẹṣẹ wá, ati nkan ti kò ti iṣe lati igbãni wá, wipe, Imọ mi yio duro, emi o si ṣe gbogbo ifẹ mi.

11 Ẹniti npe idì lati ilà-õrun wá: ọkunrin na ti o mu ìmọ mi ṣẹ lati ilẹ jijìn wá: lõtọ, emi ti sọ ọ, emi o si mu u ṣẹ; emi ti pinnu rẹ̀, emi o si ṣe e pẹlu.

12 Gbọ́ ti emi, ẹnyin alagidi ọkàn, ti o jinà si ododo:

13 Emi mu ododo mi sunmọ tosí; ki yio si jina rére, igbala mi ki yio si duro pẹ́: emi o si fi igbala si Sioni fun Israeli ogo mi.