Isa 56 YCE

Gbogbo Orílẹ̀-Èdè ni yóo Wà lára Àwọn Eniyan Ọlọrun

1 BAYI li Oluwa wi, Ẹ pa idajọ mọ, ẹ si ṣe ododo: nitori igbala mi fẹrẹ idé, ati ododo mi lati fi hàn.

2 Alabukun ni fun ọkunrin na ti o ṣe eyi, ati fun ọmọ enia ti o dì i mu: ti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́; ti o si pa ọwọ́ rẹ̀ mọ kuro ni ṣiṣe ibi.

3 Ti kò si jẹ ki ọmọ alejò ti o ti dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Oluwa sọ, wipe; Oluwa ti yà mi kuro ninu awọn enia rẹ̀ patapata: bẹ̃ni kò jẹ ki ìwẹ̀fà wipe, Wò o, igi gbigbẹ ni mi.

4 Nitori bayi li Oluwa wi fun awọn ìwẹfa ti nwọn pa ọjọ isimi mi mọ, ti nwọn si yàn eyi ti o wù mi, ti nwọn si di majẹmu mi mu;

5 Pe, emi o fi ipò kan fun wọn ni ile mi, ati ninu odi mi, ati orukọ ti o dara jù ti awọn ọmọkunrin ati ọmọ-obinrin lọ: emi o fi orukọ ainipẹkun fun wọn, ti a kì yio ke kuro.

6 Ati awọn ọmọ alejò ti nwọn dà ara pọ̀ mọ Oluwa, lati sìn i, ati lati fẹ orukọ Oluwa, lati jẹ iranṣẹ rẹ̀, olukuluku ẹniti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́, ti o si di majẹmu mi mu;

7 Awọn li emi o si mu wá si oke-nla mimọ́ mi, emi o si mu inu wọn dùn, ninu ile adua mi: ẹbọ sisun wọn, ati irubọ wọn, yio jẹ itẹwọgba lori pẹpẹ mi; nitori ile adua li a o ma pe ile mi fun gbogbo enia.

8 Oluwa Jehofah, ẹniti o ṣà àtanu Israeli jọ wipe, Emi o ṣà awọn ẹlomiran jọ sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn ti a ti ṣà jọ sọdọ rẹ̀.

A ti Dá Àwọn Olórí Israẹli Lẹ́bi

9 Gbogbo ẹnyin ẹranko igbẹ, ẹ wá lati pajẹ ani gbogbo ẹranko igbẹ.

10 Afọju li awọn alore rẹ̀: òpe ni gbogbo wọn, odi ajá ni nwọn, nwọn kò le igbó, nwọn a ma sùn, nwọn ndubulẹ, nwọn fẹ ma tõgbé.

11 Nitõtọ ọjẹun aja ni nwọn ti kì iyó, ati oluṣọ́ agutan ti kò moye ni nwọn: olukuluku wọn nwò ọ̀na ara wọn, olukuluku ntọju ere rẹ̀ lati ẹ̀kun rẹ̀ wá.

12 Ẹ wá, ni nwọn wi, emi o mu ọti-waini wá, a o si mu ọti-lile li amuyo; ọla yio si dabi ọjọ oni, yio si pọ̀ lọpọlọpọ.