Isa 62 YCE

1 NITORI ti Sioni emi kì yio dakẹ, ati nitori ti Jerusalemu emi kì yio simi, titi ododo rẹ̀ yio fi jade bi titan imọlẹ, ati igbala rẹ̀ bi fitila ti njó.

2 Ati awọn Keferi yio ri ododo rẹ, ati gbogbo ọba yio ri ogo rẹ: a o si fi orukọ titun pè ọ, eyiti ẹnu Oluwa yio darukọ.

3 Iwọ o jẹ ade ogo pẹlu li ọwọ́ Oluwa, ati adé oyè ọba li ọwọ́ Ọlọrun rẹ.

4 A ki yio pè ọ ni Ikọ̀silẹ mọ́, bẹ̃ni a ki yio pè ilẹ rẹ ni Ahoro mọ: ṣugbọn a o pè ọ ni Hefsiba: ati ilẹ rẹ ni Beula: nitori inu Oluwa dùn si ọ, a o si gbe ilẹ rẹ ni iyawo.

5 Gẹgẹ bi ọdọmọkunrin ti igbé wundia ni iyawo, bẹ̃ni awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio gbe ọ ni iyawo: ati bi ọkọ iyawo ti iyọ̀ si iyawo, bẹ̃ni Ọlọrun rẹ yio yọ̀ si ọ.

6 Emi ti fi awọn alore sori odi rẹ, iwọ Jerusalemu, ti kì yio pa ẹnu wọn mọ lọsan ati loru titilai: ẹnyin ti nṣe iranti Oluwa, ẹ máṣe dakẹ.

7 Ẹ máṣe fun u ni isimi, titi yio fi fi idi Jerusalemu mulẹ, ti yio ṣe e ni iyìn li aiye.

8 Oluwa ti fi apá ọtun rẹ̀, ati apá agbara rẹ̀ bura, Lõtọ emi kì yio fi ọkà rẹ ṣe onjẹ fun awọn ọta rẹ mọ, bẹ̃ni awọn ọmọ ajeji kì yio mu ọti-waini rẹ, eyi ti iwọ ti ṣíṣẹ fun.

9 Ṣugbọn awọn ti o ṣà a jọ yio jẹ ẹ, nwọn o si yìn Oluwa; ati awọn ti nkó o jọ yio mu u, ninu ãfin mimọ́ mi.

10 Ẹ kọja lọ, ẹ kọja li ẹnu bode; tun ọ̀na awọn enia ṣe; kọ bèbe, kọ bèbe opopo; ṣà okuta wọnni kuro, gbe ọpagun ró fun awọn enia.

11 Kiyesi i, Oluwa ti kede titi de opin aiye: Ẹ wi fun ọmọbinrin Sioni pe, Wo o, igbala rẹ de; wo o, ère rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀, ati ẹsan rẹ̀ niwaju rẹ̀.

12 A o si ma pè wọn ni, Enia mimọ́, Ẹni-irapada Oluwa: a o si ma pè ọ ni, Iwári, Ilu aikọ̀silẹ.