Isa 23 YCE

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Tire

1 Ọ̀RỌ-ìmọ niti Tire. Hu, ẹnyin ọkọ̀ Tarṣiṣi; nitoriti a o sọ ọ di ahoro, tobẹ̃ ti kò si ile, kò si ibi wiwọ̀: a fi hàn fun wọn lati ilẹ Kittimu.

2 Ẹ duro jẹ, ẹnyin olugbé erekùṣu; iwọ ẹniti awọn oniṣowo Sidoni, ti nre okun kọja ti kún.

3 Ati nipa omi nla iru Sihori, ikorè odò, ni owo ọdun rẹ̀; on ni ọjà awọn orilẹ-ède.

4 Ki oju ki o tì ọ, Iwọ Sidoni: nitori okun ti sọ̀rọ, ani agbara okun, wipe, Emi kò rọbi, bẹ̃ni emi kò bi ọmọ, bẹ̃li emi kò tọ́ ọdọmọkunrin dàgba, bẹ̃ni emi kò tọ́ wundia dàgba.

5 Gẹgẹ bi ihìn niti Egipti, bẹ̃ni ara yio ro wọn goro ni ihìn Tire.

6 Ẹ kọja si Tarṣiṣi; hu, ẹnyin olugbé erekùṣu.

7 Eyi ha ni ilu ayọ̀ fun nyin, ti o ti wà lati ọjọ jọjọ? ẹsẹ on tikara rẹ̀ yio rù u lọ si ọna jijìn rére lati ṣe atipó.

8 Tali o ti gbìmọ yi si Tire, ilu ade, awọn oniṣòwo ẹniti o jẹ ọmọ-alade, awọn alajapá ẹniti o jẹ ọlọla aiye?

9 Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pete rẹ̀, lati sọ irera gbogbo ogo di aimọ́, lati sọ gbogbo awọn ọlọla aiye di ẹ̀gan.

10 La ilẹ rẹ ja bi odò, iwọ ọmọbinrin Tarṣiṣi: àmure kò si mọ́.

11 O nà ọwọ́ rẹ̀ jade si oju okun, o mì awọn ijọba: Oluwa ti pa aṣẹ niti Kenaani, lati run agbàra inu rẹ̀.

12 On si wipe, Iwọ kò gbọdọ yọ̀ mọ, iwọ wundia ti a ni lara, ọmọbinrin Sidoni; dide rekọja lọ si Kittimu, nibẹ pẹlu iwọ kì yio ri isimi.

13 Wò ilẹ awọn ara Kaldea; awọn enia yi kò ti si ri, titi awọn ara Assiria tẹ̀ ẹ dó fun awọn ti ngbe aginju: nwọn kọ́ ile-iṣọ́ inu rẹ̀, nwọn si kọ́ ãfin inu rẹ̀; on si pa a run.

14 Hu, ẹnyin ọkọ̀ Tarṣiṣi: nitori a sọ agbara nyin di ahoro.

15 Yio si ṣe li ọjọ na, ni a o gbagbe Tire li ãdọrin ọdun, gẹgẹ bi ọjọ ọba kan: lẹhin ãdọrin ọdun ni Tire yio kọrin bi panṣaga obinrin.

16 Mu harpu kan, kiri ilu lọ, iwọ panṣaga obinrin ti a ti gbagbe; dá orin didùn: kọ orin pupọ̀ ki a le ranti rẹ.

17 Yio si ṣe li ẹhìn ãdọrin ọdun, ni Oluwa yio bẹ̀ Tire wò, yio si yipadà si ọ̀ya rẹ̀, yio si ba gbogbo ijọba aiye yi ti o wà lori ilẹ ṣe àgbere.

18 Ọjà rẹ̀ ati ọ̀ya rẹ̀ yio jẹ mimọ́ si Oluwa: a kì yio fi ṣura, bẹ̃li a ki yio tò o jọ; nitori ọjà rẹ̀ yio jẹ ti awọn ti ngbe iwaju Oluwa, lati jẹ ajẹtẹrùn, ati fun aṣọ daradara.