Isa 13 YCE

Ọlọrun Yóo Jẹ Babiloni Níyà

1 Ọ̀RỌ-ìmọ niti Babiloni ti Isaiah ọmọ Amosi ri.

2 Ẹ gbe ọpágun soke lori oke giga, ẹ kọ si wọn, ẹ juwọ, ki nwọn ba le lọ sinu ẹnu-odi awọn ọlọla.

3 Emi ti paṣẹ fun awọn temi ti a yà si mimọ́, emi ti pe awọn alagbara mi pẹlu fun ibinu mi, ani awọn ti nwọn yọ̀ ninu ọlanla mi.

4 Ariwo ọ̀pọlọpọ lori oke, gẹgẹ bi ti enia pupọ̀: ariwo rudurudu ti ijọba awọn orilẹ-ède, ti a kojọ pọ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun gbá ogun awọn ọmọ-ogun jọ.

5 Nwọn ti ilẹ okerè wá, lati ipẹkun ọrun, ani, Oluwa, ati ohun-elò ibinu rẹ̀, lati pa gbogbo ilẹ run.

6 Ẹ hu; nitori ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ; yio de bi iparun lati ọdọ Olodumare wá.

7 Nitorina gbogbo ọwọ́ yio rọ, ọkàn olukuluku enia yio si di yiyọ́.

8 Nwọn o si bẹ̀ru: irora ati ikãnu yio dì wọn mu; nwọn o wà ni irora bi obinrin ti nrọbi: ẹnu yio yà ẹnikan si ẹnikeji rẹ̀; oju wọn yio dabi ọwọ́-iná.

9 Kiyesi i, ọjọ Oluwa mbọ̀ wá, o ni ibi ti on ti ikannú ati ibinu gbigboná, lati sọ ilẹ na di ahoro: yio si pa awọn ẹlẹṣẹ run kuro ninu rẹ̀.

10 Nitori awọn iràwọ ọrun, ati iṣùpọ iràwọ inu rẹ̀ kì yio tàn imọlẹ wọn: õrun yio ṣu okùnkun ni ijadelọ rẹ̀, oṣùpa kì yio si mu ki imọlẹ rẹ̀ tàn.

11 Emi o si bẹ̀ ibi wò lara aiye, ati aiṣedẽde lara awọn enia buburu; emi o si mu ki igberaga awọn agberaga ki o mọ, emi o si mu igberaga awọn alagbara rẹ̀ silẹ.

12 Emi o mu ki ọkunrin kan ṣọwọ́n ju wura lọ; ani enia kan ju wura Ofiri daradara.

13 Nitorina emi o mu ọrun mì titi, ilẹ aiye yio si ṣipò rẹ̀ pada, ninu ibinu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati li ọjọ ibinu gbigbona rẹ̀.

14 Yio si dabi abo agbọ̀nrin ti a nlepa, ati bi agutan ti ẹnikan kò gbajọ: olukuluku wọn o yipada si enia rẹ̀, olukuluku yio si sa si ilẹ rẹ̀.

15 Ẹnikẹni ti a ri li a o gun li agunyọ; ẹnikẹni ti o si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ wọn yio ti ipa idà ṣubu.

16 Ọmọ wọn pẹlu li a o fọ́ tũtu loju ara wọn; a o si kó wọn ni ile, a o si fi agbara bà obinrin wọn jẹ́;

17 Kiyesi i, emi o gbe awọn ara Media dide si wọn, ti ki yio ka fadakà si; bi o si ṣe ti wura, nwọn ki yio ni inu didùn si i.

18 Ọrun wọn pẹlu yio fọ́ awọn ọdọmọkunrin tũtũ; nwọn ki yio ṣãnu fun ọmọ-inu: oju wọn kì yio dá ọmọde si.

19 Ati Babiloni, ogo ijọba gbogbo, ẹwà ogo Kaldea, yio dabi igbati Ọlọrun bi Sodomu on Gomorra ṣubu.

20 A kì yio tẹ̀ ẹ dó mọ, bẹ̃ni a kì yio si gbe ibẹ̀ mọ lati irandiran: bẹ̃ni awọn ara Arabia kì yio pagọ nibẹ mọ; bẹ̃ni awọn oluṣọ-agutan kì yio kọ́ agbo wọn nibẹ mọ.

21 Ṣugbọn ẹranko igbẹ yio dubulẹ nibẹ; ile wọn yio si kun fun òwiwí, abo ogòngo yio ma gbe ibẹ, ọ̀rọ̀ yio si ma jo nibẹ.

22 Awọn ọ̀wawa yio si ma ke ninu ãfin wọn, ati dragoni ninu gbọ̀ngàn wọn daradara: ìgba rẹ̀ si sunmọ etile, a kì yio si fa ọjọ rẹ̀ gùn.