Isa 52 YCE

Ọlọrun Yóo Gba Jerusalẹmu

1 JI! ji! gbe agbara rẹ wọ̀, iwọ Sioni; gbe aṣọ ogo rẹ wọ̀, iwọ Jerusalemu, ilu mimọ́: nitori lati igbayi lọ, alaikọla on alaimọ́ kì yio wọ̀ inu rẹ mọ.

2 Gbọ̀n ekuru kuro li ara rẹ, dide, joko, iwọ Jerusalemu: tú ọjá kuro li ọrùn rẹ, iwọ ondè ọmọbinrin Sioni.

3 Nitori bayi li Oluwa wi, a ti tà nyin lọfẹ, a o si rà nyin pada laisanwo.

4 Nitori bayi li Oluwa Jehofa wi, Awọn enia mi sọkalẹ lọ si Egipti li atijọ lati ṣe atipo nibẹ; ara Assiria si ni wọn lara lainidi.

5 Njẹ nisisiyi, Oluwa wipe, Kini mo nṣe nihin, ti a kó awọn enia mi lọ lọfẹ? awọn ti o jọba wọn mu nwọn kigbe, li Oluwa wi; titi lojojumọ li a si nsọ̀rọ odì si orukọ mi.

6 Nitorina awọn enia mi yio mọ̀ orukọ mi li ọjọ na: nitori emi li ẹniti nsọrọ: kiyesi i, emi ni.

7 Ẹsẹ ẹniti o mu ihinrere wá ti dara to lori awọn oke, ti nkede alafia; ti nmu ihìn rere ohun rere wá, ti nkede igbala; ti o wi fun Sioni pe, Ọlọrun rẹ̀ njọba!

8 Awọn alóre rẹ yio gbe ohùn soke; nwọn o jumọ fi ohùn kọrin: nitori nwọn o ri li ojukoju, nigbati Oluwa ba mu Sioni pada.

9 Bú si ayọ̀, ẹ jumọ kọrin, ẹnyin ibi ahoro Jerusalemu: nitori Oluwa ti tù awọn enia rẹ̀ ninu, o ti rà Jerusalemu pada.

10 Oluwa ti fi apá mimọ́ rẹ̀ hàn li oju gbogbo awọn orilẹ-ède; gbogbo opin aiye yio si ri igbala Ọlọrun wa.

11 Ẹ fà sẹhin, é fà sẹhin, é jade kuro lãrin rẹ̀; ẹ má fọwọ kàn ohun aimọ́ kan: ẹ kuro lãrin rẹ̀, ẹ jẹ mimọ́, ẹnyin ti ngbe ohun-èlo Oluwa.

12 Nitori ẹ kì yio yara jade, bẹ̃ni ẹ kì yio fi isare lọ; nitori Oluwa yio ṣãju nyin; Ọlọrun Israeli yio si kó nyin jọ.

Iranṣẹ tí Ń Jìyà

13 Kiyesi i, iranṣẹ mi yio fi oye bá ni lò; a o gbe e ga, a o si gbe e leke, on o si ga gidigidi.

14 Gẹgẹ bi ẹnu rẹ ti yà ọ̀pọlọpọ enia, a bà oju rẹ̀ jẹ ju ti ẹnikẹni lọ, ati irisi rẹ̀ ju ti ọmọ enia lọ.

15 Bẹ̃ni yio buwọ́n ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède; awọn ọba yio pa ẹnu wọn mọ si i, nitori eyi ti a kò ti sọ fun wọn ni nwọn o ri; ati eyi ti nwọn kò ti gbọ́ ni nwọn o rò.