Isa 22 YCE

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerusalẹmu

1 Ọ̀RỌ-ìmọ niti afonifoji ojuran. Kili o ṣe ọ nisisiyi, ti iwọ fi gùn ori ile lọ patapata?

2 Iwọ ti o kún fun ìrukerudo, ilu aitòro, ilu ayọ̀: a kò fi idà pa awọn okú rẹ, bẹ̃ni nwọn kò kú li ogun.

3 Gbogbo awọn alakoso rẹ ti jumọ sa lọ, awọn tafàtafà ti dì wọn ni igbekun: gbogbo awọn ti a ri ninu rẹ li a dì jọ, ti o ti sa lati okere wá.

4 Nitorina li emi ṣe wipe, Mu oju kuro lara mi; emi o sọkun kikoro, má ṣe ãpọn lati tù mi ni inu, nitori iparun ti o ba ọmọbinrin enia mi.

5 Nitori ọjọ wahála ni, ati itẹmọlẹ, ati idãmu, nipa Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun ni afonifoji ojuran, o nwó odi palẹ, o si nkigbe si oke-nla.

6 Elamu ru apó pẹlu kẹkẹ́ enia ati ẹlẹṣin, Kiri si na asà silẹ.

7 Yio si ṣe, afonifoji àṣayan rẹ yio kún fun kẹkẹ́, awọn ẹlẹṣin yio si tẹ́ ogun niha ẹnu odi.

8 On si ri iboju Juda, iwọ si wò li ọjọ na ihamọra ile igbó.

9 Ẹnyin ti ri oju-iho ilu Dafidi pẹlu, pe, nwọn pọ̀: ẹnyin si gbá omi ikudu isalẹ jọ.

10 Ẹnyin ti kà iye ile Jerusalemu, awọn ile na li ẹnyin biwó lati mu odi le.

11 Ẹnyin pẹlu ti wà yàra lãrin odi meji fun omi ikudu atijọ: ṣugbọn ẹnyin kò wò ẹniti o ṣe e, bẹ̃ni ẹ kò si buyìn fun ẹniti o ṣe e nigbãni,

12 Ati li ọjọ na ni Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio pè lati sọkun, ati lati ṣọ̀fọ, ati lati fá ori, ati lati sán aṣọ ọ̀fọ.

13 Si kiyesi i, ayọ̀ ati inu-didùn, pipa malũ, ati pipa agutan, jijẹ ẹran, ati mimu ọti-waini: ẹ jẹ ki a ma jẹ, ki a si ma mu; nitori ọla li awa o kú.

14 Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ li eti mi, pe, Nitõtọ, a kì yio fọ̀ aiṣedede yi kuro lara nyin titi ẹnyin o fi kú, li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

Ìkìlọ̀ fún Ṣebna

15 Bayi li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, Lọ, tọ olutọju yi lọ, ani tọ Ṣebna lọ, ti iṣe olori ile,

16 Si wipe, Kili o ni nihin? ati tali o ni nihin, ti iwọ fi wà ibojì nihin bi ẹniti o wà ibojì fun ara rẹ̀ nibi giga, ti o si gbẹ́ ibugbé fun ara rẹ̀ ninu apáta?

17 Kiyesi i, Oluwa yio fi sisọ agbara sọ ọ nù, yio si bò ọ mọlẹ.

18 Yio wé ọ li ewé bi ẹni wé lawàni bi ohun ṣiṣù ti a o fi sọ òko si ilẹ titobi: nibẹ ni iwọ o kú, ati nibẹ ni kẹkẹ́ ogo rẹ yio jẹ ìtiju ile oluwa rẹ.

19 Emi o si le ọ jade kuro ni ibujoko rẹ, yio tilẹ wọ́ ọ kuro ni ipò rẹ.

20 Yio si ṣe li ọjọ na, ni emi o pè Eliakimu iranṣẹ mi ọmọ Hilkiah.

21 Emi o si fi aṣọ-igunwà rẹ wọ̀ ọ, emi o si fi àmure rẹ dì i, emi o si fi ijọba rẹ le e li ọwọ́: on o si jẹ baba fun awọn olugbé Jerusalemu, ati fun ile Juda.

22 Iṣikà ile Dafidi li emi o fi le èjiká rẹ̀: yio si ṣí, kò si ẹniti yio tì; on o si tì, kò si si ẹniti yio ṣí.

23 Emi o si kàn a bi iṣó ni ibi ti o le, on o jẹ fun itẹ ogo fun ile baba rẹ̀.

24 Gbogbo ogo ile baba rẹ̀ ni nwọn o si fi kọ́ ọ li ọrùn, ati ọmọ ati eso, gbogbo ohun-elò ife titi de ago ọti.

25 Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Li ọjọ na, ni a o ṣi iṣó ti a kàn mọ ibi ti o le ni ipò, a o si ke e lu ilẹ, yio si ṣubu; ẹrù ara rẹ̀ li a o ké kuro: nitori Oluwa ti sọ ọ.