1 O si ṣe, nigbati Hesekiah ọba gbọ́, o fà aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ bora, o si lọ sinu ile Oluwa.
2 O si ran Eliakimu, ti o ṣe olutọju ile, ati Ṣebna akọwe, ati awọn agba alufa ti nwọn fi aṣọ ọ̀fọ bora, sọdọ Isaiah woli, ọmọ Amosi.
3 Nwọn si wi fun u pe, Bayi ni Hesekiah wi, Oni jẹ ọjọ wahalà, ati ibawi, ati ẹgàn: nitori awọn ọmọ de igbà ibí, agbara kò si si lati bí wọn.
4 Bọya Oluwa Ọlọrun rẹ yio gbọ́ ọ̀rọ Rabṣake, ẹniti oluwa rẹ̀ ọba Assiria ti rán lati gàn Ọlọrun alãyè, yio si ba ọ̀rọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ ti gbọ́ wi: nitorina gbe adura rẹ soke fun awọn iyokù ti o kù.
5 Bẹ̃ni awọn iranṣẹ Hesekiah ọba wá sọdọ Isaiah.
6 Isaiah si wi fun wọn pe, Bayi ni ki ẹ wi fun oluwa nyin, pe, Bayi ni Oluwa wi, Máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ ti iwọ ti gbọ́, nipa eyiti awọn iranṣẹ ọba Assiria ti fi sọ̀rọ buburu si mi.
7 Wò o, emi o fi ẽmi kan sinu rẹ̀, on o si gbọ́ iró kan, yio si pada si ilu on tikalarẹ̀; emi o si mu ki o ti ipa idà ṣubu ni ilẹ on tikalarẹ̀.
8 Bẹ̃ni Rabṣake padà, o si ba ọba Assiria mba Libna jagun: nitori ti o ti gbọ́ pe o ti kuro ni Lakiṣi.
9 O si gbọ́ a nwi niti Tirhaka ọba Etiopia, pe, O mbọ̀ wá ba iwọ jagun. Nigbati o si gbọ́, o rán awọn ikọ̀ lọ sọdọ Hesekiah, wipe,
10 Bayi ni ki ẹ wi fun Hesekiah ọba Juda, pe, Má jẹ ki Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ gbẹkẹle, ki o tàn ọ jẹ, wipe, A kì yio fi Jerusalemu le ọba Assiria lọwọ.
11 Kiyesi i, iwọ ti gbọ́ ohun ti awọn ọba Assiria ti ṣe si ilẹ gbogbo bi nwọn ti pa wọn run patapata: a o si gbà iwọ bi?
12 Oriṣa awọn orilẹ-ède ha gbà awọn ti awọn baba mi ti parun bi? bi Gosani, ati Harani ati Resefu, ati awọn ọmọ Edeni ti nwọn ti wà ni Telassari?
13 Nibo ni ọba Hamati wà, ati ọba Arfadi, ati ọba ilu Sefarfaimu, Hena, ati Ifa?
14 Hesekiah si gbà iwe na lọwọ awọn ikọ̀, o si kà a: Hesekiah si gòke lọ si ile Oluwa, o si tẹ́ ẹ siwaju Oluwa.
15 Hesekiah si gbadura si Oluwa, wipe,
16 Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, ti ngbe ãrin awọn kerubu, iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikan, ninu gbogbo ijọba aiye: iwọ li o dá ọrun on aiye.
17 Dẹti rẹ silẹ, Oluwa, ki o si gbọ́; ṣi oju rẹ, Oluwa, ki o si wò: si gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Senakeribu, ti o ranṣẹ lati kẹgàn Ọlọrun alãyè.
18 Lõtọ ni, Oluwa, awọn ọba Assiria ti sọ gbogbo orilẹ-ède di ahoro, ati ilẹ wọn,
19 Nwọn si ti sọ awọn òriṣa wọn sinu iná: nitori ọlọrun ki nwọn iṣe, ṣugbọn iṣẹ ọwọ́ enia ni, igi ati òkuta: nitorina ni nwọn ṣe pa wọn run.
20 Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa lọwọ rẹ̀, ki gbogbo ijọba aiye le mọ̀ pe iwọ ni Oluwa, ani iwọ nikanṣoṣo.
21 Nigbana ni Isaiah ọmọ Amosi ranṣẹ si Hesekiah, wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niwọ̀n bi iwọ ti gbadura si mi niti Sennakeribu ọba Assiria:
22 Eyi ni ọ̀rọ ti Oluwa ti sọ niti rẹ̀: Wundia, ọmọbinrin Sioni, ti kẹ́gàn rẹ, o si ti fi ọ rẹrin ẹlẹyà; ọmọbinrin Jerusalemu ti mì ori rẹ̀ si ọ.
23 Tani iwọ kẹgàn ti o si sọ̀rọ buburu si? tani iwọ si gbe oju rẹ ga si, ti o si gbe oju rẹ soke gangan? si Ẹni-Mimọ́ Israeli ni.
24 Nipasẹ awọn iranṣẹ rẹ li o ti kẹgàn Oluwa, ti o si ti wipe, Ni ọ̀pọlọpọ kẹkẹ́ mi, emi ti goke wá si oke awọn oke giga, si ẹba Lebanoni; emi o si ke igi kedari rẹ̀ giga lulẹ, ati ãyò igi firi rẹ̀, emi o si wá si ẹnu agbègbe rẹ̀, ati si igbó Karmeli rẹ̀.
25 Emi ti wà kanga, mo si ti mu omi; atẹlẹsẹ mi ni mo si ti fi mu gbogbo odò ibi ihamọ gbẹ.
26 Iwọ kò ti gbọ́ ri pe, lai emi li o ti ṣe e, ati pe emi li o ti dá a nigba atijọ? nisisiyi mo mu u ṣẹ, ki iwọ ki o sọ ilu-nla olodi dahoro, di okiti iparun.
27 Nitorina ni awọn olugbé wọn fi ṣe alainipa, aiya fò wọn, nwọn si dãmu: nwọn dabi koriko igbẹ, ati bi ewebẹ̀ tutù, bi koriko lori okè ilé, ati bi ọkà ti igbẹ ki o to dàgba soke.
28 Ṣugbọn mo mọ̀ ibugbe rẹ, ijadelọ rẹ, ati iwọle rẹ, ati irúnu rẹ si mi.
29 Nitori irúnu rẹ si mi, ati igberaga rẹ, ti goke wá si eti mi, nitorina ni emi o ṣe fi ìwọ mi kọ́ ọ ni imú, ati ijanu mi si ète rẹ, emi o si mu ọ pada li ọ̀na ti o ba wá.
30 Eyi ni o si jẹ àmi fun ọ, Ẹ jẹ ilalẹ̀hu li ọdun yi; ati li ọdun keji eyiti o sọ jade ninu ọkanna: ati li ọdun kẹta ẹ fọnrugbìn, ki ẹ si kore, ki ẹ si gbìn ọgba àjara, ki ẹ si jẹ eso wọn.
31 Ati iyokù ti o sala ninu ile Juda yio tun fi gbòngbo mulẹ nisalẹ, yio si so eso loke:
32 Nitori lati Jerusalemu ni iyokù yio jade lọ, ati awọn ti o sala lati oke Sioni wá: itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi.
33 Nitorina bayi ni Oluwa wi niti ọba Assiria, on kì yio wá si ilu yi, bẹ̃ni kì yio ta ọfà kan sibẹ, kì yio si mu asà wá siwaju rẹ̀, bẹ̃ni kì yio wà odi tì i.
34 Li ọ̀na ti o ba wá, li ọkanna ni yio bá padà, kò si ni wá si ilu yi, li Oluwa wi.
35 Nitori emi o dãbo bò ilu yi lati gbà a nitoriti emi tikala mi, ati nitoriti Dafidi iranṣẹ mi.
36 Angeli Oluwa si jade lọ, o si pa ọkẹ́ mẹsan o le ẹgbẹ̃dọgbọn ni budo awọn ara Assiria; nigbati nwọn si dide lowurọ kùtukutu, kiyesi i, gbogbo wọn jẹ okú.
37 Bẹ̃ni Sennakeribu ọba Assiria mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n, o si lọ, o si padà, o si ngbe Ninefe.
38 O si di igbati o ṣe, bi o ti ntẹriba ni ile Nisroki oriṣa rẹ̀, ni Adrammeleki ati Ṣaresari awọn ọmọ rẹ̀ fi idà pa a; nwọn si salà si ilẹ Armenia: Esarhaddoni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.