Isa 26 YCE

Orin Ìgbàlà

1 LI ọjọ na li a o kọ orin yi ni ilẹ Juda; Awa ní ilu agbara; igbala li Ọlọrun yio yàn fun odi ati ãbo.

2 Ẹ ṣi ilẹkun bodè silẹ, ki orilẹ-ède ododo ti nṣọ́ otitọ ba le wọ̀ ile.

3 Iwọ o pa a mọ li alafia pipé, ọkàn ẹniti o simi le ọ: nitoriti o gbẹkẹle ọ.

4 Ẹ gbẹkẹle Oluwa titi lai: nitori Oluwa Jehofa li apata aiyeraiye:

5 Nitori o rẹ̀ awọn ti ngbe oke giga silẹ; ilu giga, o mu u wálẹ; o mu u wálẹ; ani si ilẹ; o mu u de inu ekuru.

6 Ẹsẹ yio tẹ̀ ẹ mọlẹ, ani ẹsẹ awọn talaka, ati ìṣísẹ̀ awọn alaini.

7 Ọ̀na awọn olõtọ ododo ni: iwọ, olõtọ-julọ, ti wọ̀n ipa-ọ̀na awọn olõtọ.

8 Nitõtọ, Oluwa, li ọ̀na idajọ rẹ, li awa duro de ọ: ifẹ́ ọkàn wa ni si orukọ rẹ, ati si iranti rẹ.

9 Ọkàn mi li emi fi ṣe afẹ̃ri rẹ li oru; nitõtọ, pẹlu ẹmi mi ninu mi li emi o wá ọ ni kutùkutù; nitori nigbati idajọ rẹ mbẹ ni ilẹ, awọn ti mbẹ li aiye yio kọ́ ododo.

10 Bi a ba fi ojurere hàn enia buburu, kì yio kọ́ ododo: ni ilẹ iduroṣinṣin li on o hùwa aiṣõtọ, kì yio si ri ọlanla Oluwa.

11 Oluwa, ọwọ́ rẹ gbe soke, nwọn kì yio ri, ṣugbọn nwọn o ri, oju o si tì wọn nitori ilara wọn si awọn enia; nitõtọ, iná awọn ọta rẹ yio jẹ wọn run.

12 Oluwa, iwọ o fi idi alafia mulẹ fun wa: pẹlupẹlu nitori iwọ li o ti ṣe gbogbo iṣẹ wa fun wa.

13 Oluwa Ọlọrun wa, awọn oluwa miran lẹhin rẹ ti jọba lori wa: ṣugbọn nipa rẹ nikan li awa o da orukọ rẹ sọ.

14 Awọn okú, nwọn kì yio yè; awọn ti ngbe isà-okú, nwọn kì yio dide; nitorina ni iwọ ṣe bẹ̀ wọn wò ti o si pa wọn run, ti o si mu ki gbogbo iranti wọn parun.

15 Iwọ ti mu orilẹ-ède bi si i, Oluwa, iwọ ti mu orilẹ-ède bi si i; iwọ ti di ẹni-ãyin li ogo: iwọ ti sún gbogbo ãlà siwaju.

16 Oluwa, ninu wahala ni nwọn wá ọ, nwọn gbadura wúyẹ́wúyẹ́ nigbati ibawi rẹ wà lara wọn.

17 Gẹgẹ bi aboyun, ti o sunmọ akoko ibi rẹ̀, ti wà ni irora, ti o si kigbe ninu irora rẹ̀; bẹ̃li awa ti wà li oju rẹ, Oluwa.

18 Awa ti loyun, awa ti wà ni irora, o si dabi ẹnipe awa ti bi ẹfũfu; awa kò ṣiṣẹ igbala kan lori ilẹ, bẹ̃ni awọn ti ngbe aiye kò ṣubu.

19 Awọn okú rẹ yio yè, okú mi, nwọn o dide. Ẹ ji, ẹ si kọrin, ẹnyin ti ngbe inu ekuru: nitori ìri rẹ ìri ewebẹ̀ ni, ilẹ yio si sọ awọn okú jade.

Ìdájọ́ ati Ìmúpadàbọ̀sípò

20 Wá, enia mi, wọ̀ inu iyẹ̀wu rẹ lọ, si se ilẹkun rẹ mọ ara rẹ: fi ara rẹ pamọ bi ẹnipe ni iṣẹ́ju kan, titi ibinu na fi rekọja.

21 Nitorina, kiye si i, Oluwa ti ipò rẹ̀ jade lati bẹ̀ aiṣedede ẹniti ngbe ori ilẹ wo lori ilẹ; ilẹ pẹlu yio fi ẹ̀jẹ rẹ̀ hàn, kì yio si bo okú rẹ̀ mọ.