4 Ṣugbọn bi mo ti fi wọn silẹ gẹrẹ ni mo ri ẹniti ọkàn mi fẹ: mo dì i mu, emi kò si jọ̃rẹ̀ lọwọ, titi mo fi mu u wá sinu ile iya mi, ati sinu iyẹwu ẹniti o loyun mi.
5 Mo fi awọn abo egbin ati awọn abo agbọnrin igbẹ fi nyin bú, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ji i, titi yio fi wù u.
6 Tani eyi ti nti ijù jade wá bi ọwọ̀n ẽfin, ti a ti fi ojia ati turari kùn lara, pẹlu gbogbo ipara olõrun oniṣowo?
7 Wo akete rẹ̀, ti iṣe ti Solomoni; ọgọta akọni enia li o yi i ka ninu awọn akọni Israeli.
8 Gbogbo wọn li o di idà mu, nwọn gbọ́n ọgbọ́n ogun: olukulùku kọ́ idà rẹ̀ nitori ẹ̀ru li oru.
9 Solomoni, ọba, ṣe akete nla fun ara rẹ̀ lati inu igi Lebanoni.
10 O fi fadaka ṣe ọwọ̀n rẹ̀, o fi wura ṣe ibi ẹhin rẹ̀, o fi elese aluko ṣe ibujoko rẹ̀, inu rẹ̀ li o fi ifẹ tẹ́ nitori awọn ọmọbinrin Jerusalemu.