1 MO de inu ọgbà mi, arabinrin mi, iyawo! mo ti kó ojia mi pẹlu õrùn didùn mi jọ; mo ti jẹ afara mi pẹlu oyin mi; mo ti mu ọti-waini mi pẹlu wàra mi: Ẹ jẹun, ẹnyin ọrẹ́; mu, ani mu amuyo, ẹnyin olufẹ.
2 Emi sùn, ṣugbọn ọkàn mi ji, ohùn olufẹ mi ni nkànkun, wipe: Ṣilẹkun fun mi, arabinrin mi, olufẹ mi, adaba mi, alailabawọn mi: nitori ori mi kún fun ìri, ati ìdi irun mi fun kikán oru.
3 Mo ti bọ́ awọtẹlẹ mi; emi o ti ṣe gbe e wọ̀? mo ti wẹ̀ ẹsẹ̀ mi; emi o ti ṣe sọ wọn di aimọ́?
4 Olufẹ mi nawọ rẹ̀ lati inu ihò ilẹkùn, inu mi sì yọ si i.
5 Emi dide lati ṣilẹkun fun olufẹ mi, ojia si nkán lọwọ mi, ati ojia olõrùn didùn ni ika mi sori idimu iṣikà.
6 Mo ṣilẹkun fun olufẹ mi; ṣugbọn olufẹ mi ti fà sẹhin, o si ti lọ: aiya pá mi nigbati o sọ̀rọ, mo wá a, ṣugbọn emi kò ri i, mo pè e, ṣugbọn on kò da mi lohùn.