1 IRAN ti Obadiah. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi niti Edomu; Awa ti gbọ́ ihìn kan lati ọdọ Oluwa wá, a si ti rán ikọ̀ kan si ãrin awọn keferi, Ẹ dide, ẹ si jẹ ki a dide ogun si i.
2 Kiyesi i, mo ti sọ iwọ di kekere larin awọn keferi: iwọ di gigàn lọpọlọpọ.
3 Irera aiya rẹ ti tàn ọ jẹ, iwọ ti ngbe inu pàlapála apáta, ibugbe ẹniti o ga: ti o nwi li ọkàn rẹ̀ pe, Tani yio mu mi sọkalẹ?
4 Bi iwọ tilẹ gbe ara rẹ ga bi idì, ati bi iwọ tilẹ tẹ́ itẹ rẹ sãrin awọn irawọ, lati ibẹ li emi o ti sọ̀ ọ kalẹ, ni Oluwa wi.
5 Bi awọn olè tọ̀ ọ wá, bi awọn ọlọṣà li oru, (bawo li a ti ke ọ kuro!) nwọn kì yio ha jale titi nwọn fi ni to? bi awọn aka-eso-ajara wá sọdọ rẹ, nwọn kì yio ha fi ẽṣẹ́ diẹ silẹ?
6 Bawo li a ti ṣawari awọn nkan Esau! bawo li a ti wá awọn ohun ikọkọ rẹ̀ jade!
7 Gbogbo awọn ẹni imulẹ rẹ ti mu ọ de opin ilẹ rẹ: awọn ti nwọn ti wà li alafia pẹlu rẹ ti tàn ọ jẹ, nwọn si bori rẹ; awọn ti o jẹ onjẹ rẹ ti fi ọgbẹ́ si abẹ rẹ: oye kò si ninu rẹ̀.
8 Oluwa wipe, li ọjọ na ki emi o run awọn ọlọgbọn kuro ni Edomu, ati imoye kuro li oke Esau?
9 Awọn alagbara rẹ yio si bẹ̀ru, iwọ Temani, nitori ki a le ke olukuluku ti ori oke Esau kuro nitori ipania.
10 Nitori ìwa-ipa si Jakobu arakunrin rẹ itiju yio bò ọ, a o si ke ọ kuro titi lai.
11 Ni ọjọ ti iwọ duro li apa keji, ni ọjọ ti awọn alejo kó awọn ogun rẹ̀ ni igbèkun lọ, ti awọn ajeji si wọ inu ibode rẹ̀, ti nwọn si ṣẹ keké lori Jerusalemu, ani iwọ wà bi ọkan ninu wọn.
12 Ṣugbọn iwọ kì ba ti ṣiju wo ọjọ arakunrin rẹ ni ọjọ ti on di ajeji; bẹ̃ni iwọ kì ba ti yọ̀ lori awọn ọmọ Juda ni ọjọ iparun wọn; bẹ̃ni iwọ kì ba ti sọ̀rọ irera ni ọjọ wahala.
13 Iwọ kì ba ti wọ inu ibode awọn enia mi lọ li ọjọ idãmú wọn; nitotọ, iwọ kì ba ti ṣiju wo ipọnju wọn li ọjọ idãmú wọn, bẹ̃ni iwọ kì ba ti gbe ọwọ́ le ohun ini wọn li ọ̀jọ idãmú wọn.
14 Bẹ̃ni iwọ kì ba ti duro ni ikorita lati ké awọn tirẹ̀ ti o ti salà kuro; bẹ̃ni iwọ kì ba ti sé awọn tirẹ̀ ti o kù li ọjọ wahala mọ.
15 Nitori ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ sori gbogbo awọn keferi: bi iwọ ti ṣe, bẹ̃li a o si ṣe si ọ: ẹsan rẹ yio si yipada sori ara rẹ.
16 Nitori bi ẹnyin ti mu lori oke mimọ́ mi, bẹ̃ni gbogbo awọn keferi yio ma mu titi, nitõtọ, nwọn o mu, nwọn o si gbemì, nwọn o si wà bi ẹnipe nwọn kò ti si.
17 Ṣugbọn igbala yio wà lori oke Sioni, yio si jẹ mimọ́, awọn ara ile Jakobu yio si ni ini wọn.
18 Ile Jakobu yio si jẹ iná, ati ile Josefu ọwọ́-iná, ati ile Esau fun akeku-koriko, nwọn o si ràn ninu wọn, nwọn o si run wọn; kì yio si sí ẹniti yio kù ni ile Esau: nitori Oluwa ti wi i.
19 Awọn ara gusu yio ni oke Esau; awọn ti pẹ̀tẹlẹ yio si ni awọn ara Filistia: nwọn o si ni oko Efraimu, ati oko Samaria: Benjamini yio si ni Gileadi.
20 Ati igbèkun ogun yi, ti awọn ọmọ Israeli ti o wà larin awọn ara Kenaani, titi de Sarefati; ati igbèkun Jerusalemu ti o wà ni Sefaradi, yio ni awọn ilu nla gusu.
21 Awọn olugbala yio si goke Sioni wá lati ṣe idajọ oke Esau; ijọba na yio si jẹ ti Oluwa.