Amo 9 YCE

Ìdájọ́ OLUWA

1 MO ri Oluwa o duro lori pẹpẹ: o si wipe, Lù itẹrigbà ilẹ̀kun, ki awọn òpo ki o le mì: si ṣá wọn li ori, gbogbo wọn; emi o si fi idà pa ẹni ikẹhìn wọn: ẹniti o sá ninu wọn, kì yio salọ gbe; ati ẹniti o sa asalà ninu wọn li a kì yio gbàla.

2 Bi nwọn tilẹ wà ilẹ lọ si ọrun-apadi, lati ibẹ̀ li ọwọ́ mi yio ti tẹ̀ wọn; bi nwọn tilẹ gùn okè ọrun lọ; lati ibẹ̀ li emi o ti mu wọn sọ̀kalẹ:

3 Ati bi nwọn tilẹ fi ara wọn pamọ li ori oke Karmeli; emi o wá wọn ri, emi o si mu wọn kuro nibẹ̀; ati bi a tilẹ fi wọn pamọ kuro niwaju mi ni isàlẹ okun; lati ibẹ̀ na li emi o ti paṣẹ fun ejò nì, on o si bù wọn jẹ:

4 Ati bi nwọn tilẹ lọ si igbèkun niwaju awọn ọta wọn, lati ibẹ̀ wá li emi o ti paṣẹ fun idà, on o si pa wọn: emi a si tẹ̀ oju mi mọ wọn lara fun ibi, kì isi ṣe fun ire.

5 Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li ẹniti o si fi ọwọ́ kan ilẹ na, yio si di yiyọ́, gbogbo awọn ti o ngbe inu rẹ̀ yio si ṣọ̀fọ: yio si rú soke patapata bi kikun omi: a o si tẹ̀ ẹ ri, bi odò Egipti.

6 On li ẹniti o kọ́ itẹ́ rẹ̀ ninu awọn ọrun, ti o si fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ ni ilẹ aiye: ẹniti o pè awọn omi okun, ti o si tú wọn jade si ori ilẹ aiye: Oluwa li orukọ rẹ̀.

7 Ẹnyin kò ha dàbi awọn ọmọ Etiopia si mi, Ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi. Emi kò ha ti mu Israeli goke ti ilẹ Egipti jade wá? ati awọn Filistini lati ilẹ Kaftori, ati awọn ara Siria lati Kiri.

8 Kiyesi i, Oluwa Ọlọrun mbẹ lara ilẹ ọba ti o kún fun ẹ̀ṣẹ, emi o si pa a run kuro lori ilẹ; ṣugbọn emi kì yio pa ile Jakobu run tan patapata, li Oluwa wi.

9 Wò o, nitori emi o paṣẹ, emi o si kù ile Israeli ninu awọn orilẹ-ède, bi ã ti kù ọkà ninu kọ̀nkọsọ, ṣugbọn woro kikini kì yio bọ́ sori ilẹ.

10 Gbogbo awọn ẹlẹṣẹ ninu enia mi yio ti ipa idà kú, ti nwipe, Ibi na kì yio le wa ba, bẹ̃ni kì yio ba wa lojijì.

Dídá Israẹli Pada Sípò Lọ́jọ́ Iwájú

11 Li ọjọ na li emi o gbe agọ Dafidi ti o ṣubu ró, emi o si dí ẹya rẹ̀; emi o si gbe ahoro rẹ̀ soke, emi o si kọ́ ọ bi ti ọjọ igbani:

12 Ki nwọn le ni iyokù Edomu ni iní, ati ti gbogbo awọn keferi, ti a pè nipa orukọ mi, li Oluwa ti o nṣe eyi wi.

13 Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa wi, ti ẹniti ntulẹ yio le ẹniti nkorè bá, ati ẹniti o ntẹ̀ eso àjara yio le ẹniti o nfunrùgbin bá; awọn oke-nla yio si kán ọti-waini didùn silẹ, gbogbo oke kékèké yio si di yiyọ́.

14 Emi o si tun mu igbèkun Israeli enia mi padà bọ̀, nwọn o si kọ́ ahoro ilu wọnni, nwọn o si ma gbe inu wọn; nwọn o si gbin ọgbà-àjara, nwọn o si mu ọti-waini wọn; nwọn o ṣe ọgbà pẹlu, nwọn o si jẹ eso inu wọn.

15 Emi o si gbìn wọn si ori ilẹ wọn, a kì yio si fà wọn tu mọ kuro ninu ilẹ wọn, ti mo ti fi fun wọn, li Oluwa Ọlọrun rẹ wi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9