Amo 8 YCE

Ìran Nípa Agbọ̀n Èso

1 BAYI li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi: si kiyesi i, agbọ̀n eso ẹrùn kan.

2 On si wipe, Amosi, kili ohun ti iwọ ri? Emi si wipe, Agbọ̀n eso ẹrùn ni. Nigbana li Oluwa wi fun mi pe, Opin de si Israeli enia mi; emi kì yio tún kọja lọdọ wọn mọ.

3 Orin inu tempeli yio si jẹ hihu li ọjọ na, li Oluwa Ọlọrun wi: okú pupọ̀ ni yio wà ni ibi gbogbo; nwọn o ma fi idakẹ jù wọn sode.

Ìparun Israẹli

4 Ẹ gbọ́ eyi, ẹnyin ti ngbe awọn alaini mì, lati sọ awọn talakà ilẹ na di alaini,

5 Ti nwipe, Nigbawo ni oṣù titún yio pari, ki awa ba le ta ọkà? ati ọjọ isimi, ki awa ba le ṣi alikama silẹ, ki a si ṣe ìwọn efà kere, ati ìwọn ṣekeli tobi, ki a si ma fi ẹ̀tan yi ìwọn padà?

6 Ki awa le fi fàdakà rà talakà, ati bàta ẹsẹ̀ mejeji rà alaini, ki a si tà eyiti o dànu ninu alikama?

7 Oluwa ti bura nipa ọlanla Jakobu pe, Nitõtọ emi kì yio gbàgbe ọkan ninu iṣẹ wọn.

8 Ilẹ na kì yio ha warìri nitori eyi, ati olukuluku ẹniti o ngbe inu rẹ̀ kì yio ha ṣọ̀fọ? yio si rú soke patapata bi kikún omi; a o si tì i jade, a o si tẹ̀ ẹ rì, gẹgẹ bi odò Egipti.

9 Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa Ọlọrun wi; emi o si mu ki õrùn ki o wọ̀ lọsan, emi o si mu aiye ṣu òkunkun li ọ̀san gangan:

10 Emi o si yi àse nyin padà si ọ̀fọ, ati orin nyin gbogbo si ohùn-rére ẹkún: emi o si mu aṣọ ọ̀fọ wá si ẹgbẹ̀ gbogbo, ati pipá ori, si gbogbo ori; emi o si ṣe e ki o dàbi iṣọ̀fọ fun ọmọ kanṣoṣo ti a bi; ati opin rẹ̀ bi ọjọ kikorò.

11 Kiyesi i, ọjọ na de, li Oluwa Ọlọrun wi, emi o rán iyàn wá si ilẹ na, kì iṣe iyàn onjẹ, tabi ongbẹ fun omi, ṣugbọn iyàn gbigbọ́ ọ̀rọ Oluwa:

12 Nwọn o si ma rìn kiri lati okun de okun, ati lati ariwa ani titi de ila-õrun, nwọn o sare siwá sẹhìn lati wá ọ̀rọ Oluwa, nwọn kì yio si ri i.

13 Li ọjọ na li awọn arẹwà wundia, ati awọn ọdọmọkunrin yio daku fun ongbẹ.

14 Awọn ti o fi ẹ̀ṣẹ Samaria bura, ti nwọn si wipe, Iwọ Dani, ọlọrun rẹ mbẹ lãyè! ati ọ̀na Beerṣeba mbẹ lãyè! ani nwọn o ṣubu, nwọn kì yio si tún dide mọ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9