Amo 2 YCE

Moabu

1 BAYI li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Moabu, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori o ti sun egungun ọba Edomu di ẽrú.

2 Ṣugbọn emi o rán iná kan sara Moabu, yio si jó ãfin Kirioti wọnni run: Moabu yio si kú pẹlu ariwo, pẹlu iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè:

3 Emi o si ké onidajọ kurò lãrin rẹ̀, emi o si pa gbogbo ọmọ-alade inu rẹ̀ pẹlu rẹ̀; li Oluwa wi.

Juda

4 Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Juda, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti gàn ofin Oluwa, nwọn kò si pa aṣẹ rẹ̀ mọ, eke wọn si ti mu wọn ṣina, eyiti awọn baba wọn ti tẹ̀le.

5 Ṣugbọn emi o rán iná kan sara Juda, yio si jó ãfin Jerusalemu wọnni run.

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Israẹli

6 Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Israeli, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn tà olododo fun fàdakà, ati talakà fun bàta ẹsẹ̀ mejeji;

7 Nwọn tẹ ori talaka sinu eruku ilẹ, nwọn si yi ọ̀na ọlọkàn tutù po: ati ọmọ ati baba rẹ̀ nwọle tọ̀ wundia kan, lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ.

8 Nwọn si dùbulẹ le aṣọ ti a fi lelẹ fun ògo lẹba olukuluku pẹpẹ, nwọn si mu ọti-waini awọn ti a yá, ni ile ọlọrun wọn.

9 Ṣugbọn mo pa ará Amori run niwaju wọn, giga ẹniti o dàbi giga igi-kedari, on si le bi igi-oaku; ṣugbọn mo pa eso rẹ̀ run lati oke wá, ati egbò rẹ̀ lati isalẹ wá.

10 Emi mu nyin goke pẹlu lati ilẹ Egipti wá, mo si sìn nyin li ogoji ọdun là aginjù ja, lati ni ilẹ awọn Amori.

11 Mo si gbe ninu ọmọkunrin nyin dide lati jẹ woli, ati ninu awọn ọdọmọkunrin nyin lati jẹ Nasarite. Bẹ̃ ki o ri, ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi.

12 Ṣugbọn ẹnyin fun awọn Nasarite ni ọti-waini mu, ẹ si paṣẹ fun awọn woli pe, Ẹ máṣe sọtẹlẹ.

13 Wò o, emi o tẹ̀ nyin mọlẹ, bi kẹkẹ́ ti o kún fun ití ti itẹ̀.

14 Nitorina sisá yio dẹti fun ẹni yiyara, onipá kì yio si mu ipa rẹ̀ le, bẹ̃ni alagbara kì yio le gba ara rẹ̀ là.

15 Bẹ̃ni tafàtafà kì yio duro; ati ẹniti o yasẹ̀ kì yio le gbà ara rẹ̀ là: bẹ̃ni ẹniti ngùn ẹṣin kì yio gbà ara rẹ̀ là:

16 Ati ẹniti o gboiyà ninu awọn alagbara yio salọ ni ihòho li ọjọ na, li Oluwa wi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9