Amo 4 YCE

1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ yi, ẹnyin ọmọ malu Baṣan, ti o wà li oke nla Samaria, ti o nni talakà lara, ti o ntẹ̀ alaini rẹ́, ti o nwi fun oluwa wọn pe, Gbe wá, ki a si mu.

2 Oluwa Ọlọrun ti bura ninu iwà-mimọ́ rẹ̀, pe, Sa wò o, ọjọ wọnni yio de ba nyin, ti on o fi ìwọ gbe nyin kuro, yio si fi ìwọ-ẹja gbe iran nyin.

3 Ati ni ibi yiya odi wọnni li ẹnyin o ba jade lọ, olukuluku niwaju rẹ̀ gan; ẹnyin o si gbe ara nyin sọ si Harmona, li Oluwa wi.

Israẹli Kọ̀, Kò kẹ́kọ̀ọ́

4 Ẹ wá si Beteli, ki ẹ si dẹṣẹ: ẹ mu irekọja nyin pọ̀ si i ni Gilgali; ẹ si mu ẹbọ nyin wá li orowurọ̀, ati idamẹwa nyin lẹhìn ọdun mẹta.

5 Ki ẹ si ru ẹbọ ọpẹ́ pẹlu iwukara, ẹ kede, ki ẹ si fi ọrẹ atinuwa lọ̀: nitori bẹ̃li ẹnyin fẹ́, ẹnyin ọmọ Israeli, li Oluwa Ọlọrun wi.

6 Emi pẹlu si ti fun nyin ni mimọ́ ehín ni gbogbo ilu nyin, ati aini onjẹ, ni ibùgbe nyin gbogbo: sibẹ̀ ẹnyin kò yipadà sọdọ mi, li Oluwa wi.

7 Ati pẹlu, emi ti fà ọwọ́ òjo sẹhìn kuro lọdọ nyin, nigbati o kù oṣù mẹta si i fun ikorè; emi si ti mu òjo rọ̀ si ilu kan, emi kò si jẹ ki o rọ̀ si ilu miràn: o rọ̀ si apakan, ibiti kò gbe rọ̀ si si rọ.

8 Bẹ̃ni ilu meji tabi mẹta nrìn lọ si ilu kan, lati mu omi: ṣugbọn kò tẹ́ wọn lọrùn: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi.

9 Mo ti fi irẹ̀danù ati imúwòdú lù nyin: nigbati ọgbà nyin ati ọgbà-àjara nyin, ati igi ọ̀pọtọ́ nyin, ati igi olifi nyin npọ̀ si i, kòkoro jẹ wọn run; sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi.

10 Mo ti rán ajàkalẹ-arùn si ãrin nyin, gẹgẹ bi ti Egipti: awọn ọdọmọkunrin nyin li emi si ti fi idà pa, nwọn si ti kó ẹṣin nyin ni igbèkun pẹlu; mo si ti jẹ ki õrùn ibùdo nyin bù soke wá si imú nyin: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi.

11 Mo ti bì ṣubu ninu nyin, bi Ọlọrun ti bì Sodomu on Gomorra ṣubu, ẹnyin si dàbi oguná ti a fà yọ kuro ninu ijoná: sibẹ̀ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi, li Oluwa wi.

12 Nitorina, bayi li emi o ṣe si ọ, iwọ Israeli: ati nitoriti emi o ṣe eyi si ọ, mura lati pade Ọlọrun rẹ, iwọ Israeli.

13 Nitori sa wò o, ẹniti o dá awọn oke nla, ti o si dá afẹ̃fẹ, ti o si sọ fun enia ohun ti erò inu rẹ̀ jasi, ti o sọ owurọ̀ di òkunkun, ti o si tẹ̀ ibi giga aiye mọlẹ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9