1 NAOMI iya-ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Ọmọbinrin mi, emi ki yio ha wá ibi isimi fun ọ, ki o le dara fun ọ?
2 Njẹ nisisiyi ibatan wa ki Boasi iṣe, ọmọbinrin ọdọ ẹniti iwọ ti mbá gbé? Kiyesi i, o nfẹ ọkà-barle li alẹ yi ni ilẹ-ipakà rẹ̀.
3 Nitorina wẹ̀, ki o si para, ki o si wọ̀ aṣọ rẹ, ki o si sọkalẹ lọ si ilẹ-ipakà: ṣugbọn má ṣe jẹ ki ọkunrin na ki o ri ọ titi on o fi jẹ ti on o si mu tán.
4 Yio si ṣe, nigbati o ba dubulẹ, ki iwọ ki o kiyesi ibi ti on o sùn si, ki iwọ ki o wọle, ki o si ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀, ki o si dubulẹ; on o si sọ ohun ti iwọ o ṣe fun ọ.
5 O si wi fun u pe, Gbogbo eyiti iwọ wi fun mi li emi o ṣe.
6 O si sọkalẹ lọ si ilẹ-ipakà na, o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti iya-ọkọ rẹ̀ palaṣẹ fun u.