File 1 YCE

1 PAULU, onde Kristi Jesu, ati Timotiu arakunrin wa, si Filemoni olufẹ ati alabaṣiṣẹ wa ọwọn,

2 Ati si Affia arabinrin wa, ati si Arkippu ọmọ-ogun ẹgbẹ wa, ati si ìjọ inu ile rẹ:

3 Ore-ọfẹ, ati alafia sí nyin, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.

Ìfẹ́ ati Igbagbọ Tí Filemoni Ní

4 Emi ndupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigbagbogbo, emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi,

5 Bi mo ti ngbọ́ ti ifẹ rẹ ati igbagbọ́ ti iwọ ni si Jesu Oluwa, ati si gbogbo awọn enia mimọ́;

6 Ki idapọ igbagbọ́ rẹ le lagbara, ni imọ ohun rere gbogbo ti mbẹ ninu nyin si Kristi.

7 Emi sá ni ayọ̀ pupọ ati itunu nitori ifẹ rẹ, nitoriti a tù ọkàn awọn enia mimọ́ lara lati ọwọ́ rẹ wá, arakunrin.

Ẹ̀bẹ̀ fún Onisimu

8 Nitorina, bi mo tilẹ ni igboiya pupọ̀ ninu Kristi lati paṣẹ ohun ti o yẹ fun ọ,

9 Ṣugbọn nitori ifẹ emi kuku bẹ̀bẹ, iru ẹni bi emi Paulu arugbo, ati nisisiyi ondè Kristi Jesu pẹlu.

10 Emi bẹ̀ ọ fun ọmọ mi, ti mo bí ninu ìde mi, Onesimu:

11 Nigbakan rí ẹniti o jẹ alailere fun ọ, ṣugbọn nisisiyi o lere fun ọ ati fun mi:

12 Ẹniti mo rán pada, ani on tikalarẹ̀, eyini ni olufẹ mi:

13 Ẹniti emi iba fẹ daduro pẹlu mi, ki o le mã ṣe iranṣẹ fun mi nipo rẹ ninu ìde ihinrere:

14 Ṣugbọn li aimọ̀ inu rẹ emi kò fẹ ṣe ohun kan; ki ore rẹ ki o má ba dabi afiyanjuṣe, bikoṣe tifẹtifẹ.

15 Nitori boya idi rẹ̀ li eyi ti o fi kuro lọdọ rẹ fun igba diẹ, ki iwọ ki o ba le ni i titi lai;

16 Kì iṣe bi ẹrú mọ, ṣugbọn o jù ẹrú lọ, arakunrin olufẹ, papa fun mi, melomelo jubẹ̃lọ fun ọ, nipa ti ara ati nipa ti Oluwa.

17 Nitorina bi iwọ ba kà mi si ẹlẹgbẹ rẹ, gbà a bi emi tikarami.

18 Ṣugbọn bi o ba ti ṣẹ̀ ọ rara, tabi ti o jẹ ọ nigbese kan, kà a si mi lọrùn.

19 Emi Paulu li o fi ọwọ́ ara mi kọ ọ, emi ó san a pada: ki emi má sọ fun ọ, bi o ti jẹ mi nigbese ara rẹ pẹlu.

20 Nitõtọ, arakunrin, jẹ ki emi ki o ni ayọ̀ rẹ ninu Oluwa: tù ọkan mi lara ninu Kristi.

21 Bi mo ti ni igbẹkẹle ni igbọràn rẹ ni mo fi kọwe si ọ: nitori mo mọ̀ pe, iwọ ó tilẹ ṣe jù bi mo ti wi lọ.

22 Ati pẹlu, pese ìbuwọ̀ silẹ dè mi; nitori mo gbẹkẹle pe nipa adura nyin, a ó fi mi fun nyin.

Ìdágbére

23 Epafra, ondè ẹlẹgbẹ mi ninu Kristi Jesu kí ọ;

24 Marku, Aristarku, Dema, Luku, awọn olubaṣiṣẹ mi kí ọ pẹlu.

25 Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa ki o wà pẹlu ẹmí nyin. Amin.

orí

1