Tit 3 YCE

Ìlànà nípa Ìwà Tí Ó Dára

1 MÃ rán wọn leti lati mã tẹriba fun awọn ijoye, ati fun awọn alaṣẹ, lati mã gbọ́ ti wọn, ati lati mã mura si iṣẹ rere gbogbo,

2 Ki nwọn má sọrọ ẹnikẹni ni ibi, ki nwọn má jẹ onija, bikoṣe ẹni pẹlẹ, ki nwọn mã fi ìwa tutù gbogbo han si gbogbo enia.

3 Nitori awa pẹlu ti jẹ were nigbakan rí, alaigbọran aṣako, ẹniti nsin onirũru ifẹkufẹ ati adùn aiye, a wà ninu arankàn ati ilara, a jẹ ẹni irira, a si nkorira awọn ọmọnikeji wa.

4 Ṣugbọn nigbati ìṣeun Ọlọrun Olugbala wa ati ifẹ rẹ̀ si enia farahan,

5 Kì iṣe nipa iṣẹ ti awa ṣe ninu ododo ṣugbọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀ li o gbà wa là, nipa ìwẹnu atúnbi ati isọdi titun Ẹmí Mimọ́,

6 Ti o dà si wa lori lọpọlọpọ nipasẹ Jesu Kristi Olugbala wa;

7 Ki a le dá wa lare nipa ore-ọfẹ rẹ̀, ki a si le sọ wa di ajogún gẹgẹ bi ireti ìye ainipẹkun.

8 Otitọ li ọ̀rọ na, emi si nfẹ ki iwọ ki o tẹnumọ nkan wọnyi gidigidi, ki awọn ti o gbà Ọlọrun gbọ́ le mã tọju ati ṣe iṣẹ rere. Nkan wọnyi dara, nwọn si ṣe anfani fun enia.

9 Ṣugbọn yà kuro ni ìbẽre wère, ati ìtan iran, ati ijiyan, ati ija nipa ti ofin; nitoripe alailere ati asan ni nwọn.

10 Ẹniti o ba ṣe aladamọ̀ lẹhin ìkilọ ikini ati ekeji, kọ̀ ọ;

11 Ki o mọ̀ pe irú ẹni bẹ̃ ti yapa, o si ṣẹ̀, o dá ara rẹ̀ lẹbi.

Gbolohun Ìparí

12 Nigbati mo ba rán Artema si ọ, tabi Tikiku, yara tọ̀ mi wá ni Nikopoli: nitori ibẹ ni mo ti pinnu lati lo akoko otutu.

13 Pese daradara fun Sena amofin ati Apollo li ọ̀na àjo wọn, ki ohunkohun maṣe kù wọn kù.

14 Ki awọn enia wa pẹlu si kọ́ lati mã ṣe iṣẹ rere fun ohun ti a kò le ṣe alaini, ki nwọn ki o má ba jẹ alaileso.

15 Gbogbo awọn ti mbẹ lọdọ mi kí ọ. Kí awọn ti o fẹ wa ninu igbagbọ́. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.

orí

1 2 3