Tit 1 YCE

Ìkíni

1 PAULU, iranṣẹ Ọlọrun, ati Aposteli Jesu Kristi, gẹgẹ bi igbagbọ́ awọn ayanfẹ Ọlọrun, ati imọ otitọ ti mbẹ gẹgẹ bi ìwa-bi-Ọlọrun,

2 Ni ireti ìye ainipẹkun, ti Ọlọrun, Ẹniti kò le ṣèké, ti ṣe ileri ṣaju ipilẹṣẹ aiye;

3 Ṣugbọn ni akokò tirẹ̀ o fi ọ̀rọ rẹ̀ hàn ninu iwasu, ti a fi le mi lọwọ gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Olugbala wa;

4 Si Titu, ọmọ mi nitõtọ nipa igbagbọ́ ti iṣe ti gbogbo enia: Ore-ọfẹ, ãnu, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá ati Kristi Jesu Olugbala wa.

Iṣẹ́ Titu ní Kirete

5 Nitori idi eyi ni mo ṣe fi ọ silẹ ni Krete, ki iwọ ki o le ṣe eto ohun ti o kù, ki o si yan awọn alagba ni olukuluku ilu, bi mo ti paṣẹ fun ọ.

6 Bi ẹnikan ba ṣe alailẹgan, ọkọ aya kan, ti o ni ọmọ ti o gbagbọ́, ti a kò fi sùn fun wọbia, ti nwọn kò si jẹ alagidi.

7 Nitori o yẹ ki biṣopu jẹ alailẹgàn, bi iriju Ọlọrun; ki o má jẹ aṣe-tinu-ẹni, oninu-fùfu, ọmuti, aluni, olojukokoro;

8 Bikoṣe olufẹ alejò ṣiṣe, olufẹ awọn enia rere, alairekọja, olõtọ, ẹni mimọ́, ẹni iwọntunwọnsi;

9 Ti o ndì ọ̀rọ otitọ mu ṣinṣin eyiti iṣe gẹgẹ bi ẹ̀kọ́, ki on ki o le mã gbani-niyanju ninu ẹ̀kọ́ ti o yè kõro, ki o si le mã da awọn asọrọ-odi lẹbi.

10 Nitoripe ọpọlọpọ awọn alagídi, awọn asọ̀rọ asan, ati awọn ẹlẹtàn ni mbẹ, papa awọn ti ikọla:

11 Awọn ẹniti a kò le ṣaipa li ẹnu mọ, nitoriti wọn nda odidi agbo ilé rú, ti nwọn nkọni ni ohun ti kò yẹ nitori ere aitọ́.

12 Ọkan ninu wọn, ani woli awọn tikarawọn, wipe, Eke ni awọn ará Krete nigbagbogbo, ẹranko buburu, ọlẹ alajẹki.

13 Otitọ li ẹrí yi. Nitorina bá wọn wi gidigidi, ki nwọn ki o le yè kõro ni igbagbọ́;

14 Ki nwọn máṣe fiyesi ìtan lasan ti awọn Ju, ati ofin awọn enia ti nwọn yipada kuro ninu otitọ.

15 Ohun gbogbo ni o mọ́ fun awọn ẹniti o mọ́, ṣugbọn fun awọn ti a sọ di ẹlẹgbin ati awọn alaigbagbọ́ kò si ohun ti o mọ́; ṣugbọn ati inu ati ẹ̀ri-ọkan wọn li a sọ di ẹgbin.

16 Nwọn jẹwọ pe nwọn mọ̀ Ọlọrun; ṣugbọn nipa iṣẹ nwọn nsẹ́ ẹ, nwọn jẹ ẹni irira, ati alaigbọran, ati niti iṣẹ rere gbogbo alainilari.

orí

1 2 3