10 Mo ni igbẹkẹle si nyin ninu Oluwa pe, ẹnyin kì yio ni ero ohun miran; ṣugbọn ẹniti nyọ nyin lẹnu yio rù idajọ tirẹ̀, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ.
11 Ṣugbọn, ara, bi emi ba nwasu ikọla sibẹ, ehatiṣe ti a nṣe inunibini si mi sibẹ? njẹ ikọsẹ agbelebu ti kuro.
12 Emi iba fẹ ki awọn ti nyọ nyin lẹnu tilẹ ké ara wọn kuro.
13 Nitori a ti pè nyin si omnira, ará; kiki pe ki ẹ máṣe lò omnira nyin fun àye sipa ti ara, ṣugbọn ẹ mã fi ifẹ sìn ọmọnikeji nyin.
14 Nitoripe a kó gbogbo ofin já ninu ọ̀rọ kan, ani ninu eyi pe; Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.
15 Ṣugbọn bi ẹnyin ba mbù ara nyin ṣán, ti ẹ si njẹ ara nyin run, ẹ kiyesara ki ẹ máṣe pa ara nyin run.
16 Njẹ mo ni, Ẹ ma rìn nipa ti Ẹmí, ẹnyin kì yio si mu ifẹkufẹ ti ara ṣẹ.