1 ARÁ, bi a tilẹ mu enia ninu iṣubu kan, ki ẹnyin ti iṣe ti Ẹmí ki o mu irú ẹni bẹ̃ bọ̀ sipò ni ẹmí iwa tutu; ki iwọ tikararẹ mã kiyesara, ki a má ba dan iwọ nã wò pẹlu.
2 Ẹ mã rù ẹrù ọmọnikeji nyin, ki ẹ si fi bẹ̃ mu ofin Kristi ṣẹ.
3 Nitori bi enia kan ba nrò ara rẹ̀ si ẹnikan, nigbati kò jẹ nkan, o ntàn ara rẹ̀ jẹ.
4 Ṣugbọn ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ̀ wò, nigbana ni yio si ni ohun iṣogo nipa ti ara rẹ̀ nikan, kì yio si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ̀.
5 Nitori olukuluku ni yio rù ẹrù ti ara rẹ̀.
6 Ṣugbọn ki ẹniti a nkọ́ ninu ọ̀rọ na mã pese ohun rere gbogbo fun ẹniti nkọni.
7 Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká.
8 Nitori ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti ara rẹ̀, nipa ti ara ni yio ká idibajẹ; ṣugbọn ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti Ẹmí, nipa ti Ẹmí ni yio ká ìye ainipẹkun.
9 Ẹ má si jẹ ki agãra da wa ni rere iṣe: nitori awa ó ká nigbati akokò ba de, bi a kò bá ṣe ãrẹ̀.
10 Njẹ bi a ti nri akoko, ẹ jẹ ki a mã ṣore fun gbogbo enia, ati pãpa fun awọn ti iṣe ara ile igbagbọ́.
11 Ẹ wò bi mo ti fi ọwọ ara mi kọwe gàdàgbà-gàdàgbà si nyin.
12 Iye awọn ti nfẹ ṣe aṣehan li ara, nwọn nrọ̀ nyin lati kọla; kiki nitoripe ki a ma ba ṣe inunibini si wọn nitori agbelebu Kristi.
13 Nitori awọn ti a kọ nilà pãpã kò pa ofin mọ́, ṣugbọn nwọn nfẹ mu nyin kọla, ki nwọn ki o le mã ṣogo ninu ara nyin.
14 Ṣugbọn ki a máṣe ri pe emi nṣogo, bikoṣe ninu agbelebu Jesu Kristi Oluwa wa, nipasẹ ẹniti a ti kàn aiye mọ agbelebu fun mi, ati emi fun aiye.
15 Nitoripe ninu Kristi Jesu ikọla kò jẹ ohun kan, tabi aikọla, bikoṣe ẹda titun.
16 Iye awọn ti o si nrìn gẹgẹ bi ìwọn yi, alafia lori wọn ati ãnu, ati lori Israeli Ọlọrun.
17 Lati isisiyi lọ, ki ẹnikẹni máṣe yọ mi lẹnu mọ́: nitori emi nrù àpá Jesu Oluwa kiri li ara mi.
18 Ará, ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa, ki o wà pẹlu ẹmí nyin. Amin.