Gal 4 YCE

1 NJẸ mo wipe, niwọn igbati arole na ba wà li ewe, kò yàtọ ninu ohunkohun si ẹrú bi o tilẹ jẹ oluwa ohun gbogbo;

2 Ṣugbọn o wà labẹ olutọju ati iriju titi fi di akokò ti baba ti yàn tẹlẹ.

3 Gẹgẹ bẹ̃ si li awa, nigbati awa wà li ewe, awa wà li ondè labẹ ipilẹṣẹ ẹda:

4 Ṣugbọn nigbati akokò kíkun na de, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ jade wá, ẹniti a bí ninu obinrin, ti a bi labẹ ofin,

5 Lati ra awọn ti mbẹ labẹ ofin pada, ki awa ki o le gbà isọdọmọ.

6 Ati nitoriti ẹnyin nṣe ọmọ, Ọlọrun si ti rán Ẹmí Ọmọ rẹ̀ wá sinu ọkàn nyin, ti nke pe, Abba, Baba.

7 Nitorina iwọ kì iṣe ẹrú mọ́, bikoṣe ọmọ; ati bi iwọ ba iṣe ọmọ, njẹ iwọ di arole Ọlọrun nipasẹ Kristi.

Paulu Ní Àníyàn fún Àwọn Ará Galatia

8 Ṣugbọn nigbati ẹnyin kò ti mọ̀ Ọlọrun rí, ẹnyin ti nsìnrú fun awọn ti kì iṣe ọlọrun nipa ẹda.

9 Ṣugbọn nisisiyi, nigbati ẹnyin ti mọ̀ Ọlọrun tan, tabi ki a sá kuku wipe, ẹ di mimọ̀ fun Ọlọrun, ẽha ti ri ti ẹ fi tun yipada si alailera ati alagbe ipilẹṣẹ ẹda, labẹ eyiti ẹnyin tun fẹ pada wa sinru?

10 Ẹnyin nkiyesi ọjọ, ati oṣù, ati akokò, ati ọdún.

11 Ẹru nyin mba mi, ki o má ba ṣe pe lasan ni mo ti ṣe lãlã lori nyin.

12 Ará, mo bẹ̀ nyin, ẹ dà bi emi; nitori emi dà bi ẹnyin: ẹnyin kò ṣe mi ni ibi kan.

13 Ṣugbọn ẹnyin mọ̀ pe ailera ara li o jẹ ki nwasu ihinrere fun nyin li akọṣe.

14 Eyiti o si jẹ idanwo fun nyin li ara mi li ẹ kò kẹgàn, bẹni ẹ kò si kọ̀; ṣugbọn ẹnyin gbà mi bi angẹli Ọlọrun, ani bi Kristi Jesu.

15 Njẹ ayọ nyin igbana ha da? nitori mo gbà ẹ̀ri nyin jẹ pe, iba ṣe iṣe, ẹ ba yọ oju nyin jade, ẹ ba si fi wọn fun mi.

16 Njẹ mo ha di ọta nyin nitori mo sọ otitọ fun nyin bi?

17 Nwọn nfi itara wá nyin, ṣugbọn ki iṣe fun rere; nwọn nfẹ já nyin kuro, ki ẹnyin ki o le mã wá wọn.

18 Ṣugbọn o dara lati mã fi itara wá ni fun rere nigbagbogbo, kì si iṣe nigbati mo wà pẹlu nyin nikan.

19 Ẹnyin ọmọ mi kekeke, ẹnyin ti mo tún nrọbi titi a o fi ṣe ẹda Kristi ninu nyin.

20 Iba wù mi lati wà lọdọ nyin nisisiyi, ki emi ki o si yi ohùn mi pada nitoripe mo dãmu nitori nyin.

Àkàwé Hagari ati Sara

21 Ẹ wi fun mi, ẹnyin ti nfẹ wà labẹ ofin, ẹ kò ha gbọ́ ofin?

22 Nitori a ti kọ ọ pe, Abrahamu ni ọmọ ọkunrin meji, ọkan lati ọdọ ẹrú-binrin, ati ọkan lati ọdọ omnira-obinrin.

23 Ṣugbọn a bí eyiti iṣe ti ẹrúbinrin nipa ti ara; ṣugbọn eyi ti omnira-obinrin li a bí nipa ileri.

24 Nkan wọnyi jẹ apẹrẹ: nitoripe awọn obinrin wọnyi ni majẹmu mejeji; ọkan lati ori oke Sinai wá, ti a bí li oko-ẹrú, ti iṣe Hagari.

25 Nitori Hagari yi ni òke Sinai Arabia, ti o si duro fun Jerusalemu ti o wà nisisiyi, ti o si wà li oko-ẹrú pẹlu awọn ọmọ rẹ̀.

26 Ṣugbọn Jerusalemu ti oke jẹ omnira, eyiti iṣe iya wa.

27 Nitori a ti kọ ọ pe, Mã yọ̀, iwọ àgan ti kò bímọ: bú si ayọ̀ ki o si kigbe soke, iwọ ti kò rọbi rí; nitori awọn ọmọ ẹni alahoro pọ̀ jù ti abilekọ lọ.

28 Njẹ ará, ọmọ ileri li awa gẹgẹ bi Isaaki.

29 Ṣugbọn bi eyiti a bí nipa ti ara ti ṣe inunibini nigbana si eyiti a bí nipa ti Ẹmi, bẹ̃ si ni nisisiyi.

30 Ṣugbọn iwe-mimọ́ ha ti wi? Lé ẹrú-binrin na jade ati ọmọ rẹ̀: nitori ọmọ ẹrú-binrin kì yio ba ọmọ omnira-obinrin jogun pọ̀.

31 Nitorina, ará, awa kì iṣe ọmọ ẹrú-binrin, bikoṣe ti omnira-obinrin.

orí

1 2 3 4 5 6