17 Ẹ̀ṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi kì yio si ranti mọ́.
18 Ṣugbọn nibiti imukuro iwọnyi ba gbé wà, irubọ fun ẹ̀ṣẹ kò si mọ́.
19 Ará, njẹ bi a ti ni igboiya lati wọ̀ inu ibi mimọ́ nipasẹ ẹ̀jẹ Jesu,
20 Nipa ọ̀na titun ati ãye, ti o yà si mimọ́ fun wa, ati lati kọja aṣọ ikele nì, eyini ni, ara rẹ̀;
21 Ati bi a ti ni alufa giga lori ile Ọlọrun;
22 Ẹ jẹ ki a fi otitọ ọkàn sunmọ tosi ni ẹ̀kún igbagbọ́, ki a si wẹ̀ ọkàn wa mọ́ kuro ninu ẹri-ọkàn buburu, ki a si fi omi mimọ́ wẹ̀ ara wa nù.
23 Ẹ jẹ ki a dì ijẹwọ ireti wa mu ṣinṣin li aiṣiyemeji; (nitoripe olõtọ li ẹniti o ṣe ileri;)