Heb 8 YCE

Olórí Alufaa ti Majẹmu Titun

1 NJẸ pataki ninu ohun ti a nsọ li eyi: Awa ni irú Olori Alufa bẹ̃, ti o joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ ọla nla ninu awọn ọrun:

2 Iranṣẹ ibi mimọ́, ati ti agọ́ tõtọ, ti Oluwa pa, kì iṣe enia.

3 Nitori a fi olukuluku olori alufa jẹ lati mã mu ẹ̀bun wá ati lati mã rubọ: nitorina olori alufa yi pẹlu kò le ṣe aini ohun ti yio fi rubọ.

4 Nisisiyi ibaṣepe o mbẹ li aiye, on kì bá tilẹ jẹ alufa, nitori awọn ti nfi ẹbun rubọ gẹgẹ bi ofin mbẹ:

5 Awọn ẹniti njọsìn fun apẹrẹ ati ojiji awọn ohun ọrun, bi a ti kọ́ Mose lati ọdọ Ọlọrun wá nigbati o fẹ pa agọ́: nitori o wipe, kiyesi ki o ṣe ohun gbogbo gẹgẹ bi apẹrẹ ti a fihàn ọ lori òke.

6 Ṣugbọn nisisiyi o ti gbà iṣẹ iranṣẹ ti o ni ọlá jù, niwọn bi o ti jẹ pe alarina majẹmu ti o dara jù ni iṣe, eyiti a fi ṣe ofin lori ileri ti o sàn jù bẹ̃ lọ.

7 Nitori ibaṣepe majẹmu iṣaju nì kò li àbuku, njẹ a kì ba ti wá àye fun ekeji.

8 Nitoriti o ri àbuku lara wọn, o wipe, Kiyesi i, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o bá ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun.

9 Kì iṣe gẹgẹ bi majẹmu ti mo ti bá awọn baba wọn dá, li ọjọ na ti mo fà wọn lọwọ lati mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti; nitoriti nwọn kò duro ninu majẹmu mi, emi kò si kà wọn si, ni Oluwa wi.

10 Nitori eyi ni majẹmu ti emi ó ba ile Israeli da lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi; Emi ó fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ wọn si ọkàn wọn: emi o si mã jẹ́ Ọlọrun fun wọn, nwọn o si mã jẹ́ enia fun mi:

11 Olukuluku kì yio si mã kọ́ ara ilu rẹ̀ ati olukuluku arakunrin rẹ̀ wipe, Mọ̀ Oluwa: nitoripe gbogbo wọn ni yio mọ̀ mi, lati kekere de àgba.

12 Nitoripe emi o ṣãnu fun aiṣododo wọn, ati ẹ̀ṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi kì yio si ranti mọ́.

13 Li eyi ti o wipe, Majẹmu titun, o ti sọ ti iṣaju di ti lailai. Ṣugbọn eyi ti o ndi ti lailai ti o si ngbó, o mura ati di asan.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13