Heb 9 YCE

Ilé Ìsìn Ti Ayé ati Ti Ọ̀run

1 NJẸ majẹmu iṣaju papa pẹlu ní ìlana ìsin, ati ibi mimọ́ ti aiye yi.

2 Nitoripe a pa agọ́ kan; eyi ti iṣaju ninu eyi ti ọpá fitila, ati tabili, ati akara ifihàn gbé wà, eyiti a npè ni ibi mimọ́.

3 Ati lẹhin aṣọ ikele keji, on ni agọ́ ti a npè ni ibi mimọ julọ;

4 Ti o ni awo turari wura, ati apoti majẹmu ti a fi wura bò yiká, ninu eyi ti ikoko wura ti o ni manna gbé wà, ati ọpá Aaroni ti o rudi, ati awọn walã majẹmu;

5 Ati lori rẹ̀ ni awọn kerubu ogo ti o ṣijibo ìtẹ́ ãnu; eyiti a kò le sọrọ rẹ̀ nisisiyi lọkọ̃kan.

6 Njẹ nigbati a ti ṣe ètò nkan wọnyi bayi, awọn alufa a mã lọ nigbakugba sinu agọ́ ekini, nwọn a mã ṣe iṣẹ ìsin.

7 Ṣugbọn sinu ekeji ni olori alufa nikan imã lọ lẹ̃kanṣoṣo li ọdún, kì iṣe li aisi ẹ̀jẹ, ti on fi rubọ fun ara rẹ̀ na, ati fun ìṣina awọn enia:

8 Ẹmí Mimọ́ ntọka eyi pé a kò ti iṣi ọ̀na ibi mimọ́ silẹ niwọn igbati agọ́ ekini ba duro.

9 Eyiti iṣe apẹrẹ fun igba isisiyi gẹgẹ bi eyiti a nmu ẹ̀bun ati ẹbọ wá, ti kò le mu olusin di pipé niti ohun ti ẹri-ọkàn,

10 Eyiti o wà ninu ohun jijẹ ati ohun mimu ati onirũru ìwẹ, ti iṣe ìlana ti ara nikan ti a fi lelẹ titi fi di igba atunṣe.

11 Ṣugbọn nigbati Kristi de bi Olori Alufa awọn ohun rere ti mbọ̀, nipaṣe agọ́ ti o tobi ti o si pé ju ti iṣaju, eyiti a kò fi ọwọ́ pa, eyini ni, ti kì iṣe ti ẹ̀da yi.

12 Bẹ̃ni kì iṣe nipasẹ ẹ̀jẹ ewurẹ ati ọmọ malu, ṣugbọn nipa ẹ̀jẹ on tikararẹ̀ o wọ ibi mimọ́ lẹ̃kanṣoṣo, lẹhin ti o ti ri idande ainipẹkun gbà fun wa.

13 Nitori bi ẹ̀jẹ akọ malu ati ewurẹ ti a fi nwọ́n awọn ti a ti sọ di alaimọ́ ba nsọ-ni-di-mimọ́ fun iwẹnumọ ara,

14 Melomelo li ẹ̀jẹ Kristi, ẹni nipa Ẹmí aiyeraiye ti a fi ara rẹ̀ rubọ si Ọlọrun li aini àbawọn, yio wẹ̀ ẹrí-ọkàn nyin mọ́ kuro ninu okú ẹṣẹ lati sìn Ọlọrun alãye?

15 Ati nitori eyi li o ṣe jẹ alarina majẹmu titun pe bi ikú ti mbẹ fun idande awọn irekọja ti o ti wà labẹ majẹmu iṣaju, ki awọn ti a ti pè le ri ileri ogún ainipẹkun gbà.

16 Nitori nibiti iwe-ogún ba gbé wà, ikú ẹniti o ṣe e kò le ṣe aisi pẹlu.

17 Nitori iwe-ogún li agbara lẹhin igbati enia ba kú: nitori kò li agbara rara nigbati ẹniti o ṣe e ba mbẹ lãye.

18 Nitorina li a kò ṣe yà majẹmu iṣaju papa si mimọ́ laisi ẹ̀jẹ.

19 Nitori nigbati Mose ti sọ gbogbo aṣẹ fun gbogbo awọn enia gẹgẹ bi ofin, o mu ẹ̀jẹ ọmọ malu ati ti ewurẹ, pẹlu omi, ati owu ododó, ati ewe hissopu, o si fi wọ́n ati iwe pãpã ati gbogbo enia,

20 Wipe, Eyi li ẹ̀jẹ majẹmu ti Ọlọrun palaṣẹ fun nyin.

21 Bẹ gẹgẹ li o si fi ẹ̀jẹ wọ́n agọ́, ati gbogbo ohun èlo ìsin.

22 O si fẹrẹ jẹ́ ohun gbogbo li a fi ẹ̀jẹ wẹ̀nu gẹgẹ bi ofin; ati laisi itajẹsilẹ kò si idariji.

Ẹbọ tí Jesu Rú Wẹ Ẹ̀ṣẹ̀ Nù

23 Nitorina a kò le ṣai fi iwọnyi wẹ̀ awọn apẹrẹ ohun ti mbẹ lọrun mọ́; ṣugbọn o yẹ ki a fi ẹbọ ti o san ju iwọnyi lọ wẹ̀ awọn ohun ọrun pãpã mọ́.

24 Nitori Kristi kò wọ̀ ibi mimọ́ ti a fi ọwọ́ ṣe lọ ti iṣe apẹrẹ ti otitọ; ṣugbọn o lọ si ọ̀run pãpã, nisisiyi lati farahan ni iwaju Ọlọrun fun wa:

25 Kì si iṣe pe ki o le mã fi ara rẹ̀ rubọ nigbakugba, bi olori alufa ti ima wọ̀ inu ibi mimọ́ lọ li ọdọ̃dún ti on ti ẹ̀jẹ ti ki ṣe tirẹ̀;

26 Bi bẹ̃kọ on kì bá ṣai mã jìya nigbakugba lati ipilẹ aiye: ṣugbọn nisisiyi li o fi ara hàn lẹ̃kanṣoṣo li opin aiye lati mu ẹ̀ṣẹ kuro nipa ẹbọ ara rẹ̀.

27 Niwọn bi a si ti fi lelẹ fun gbogbo enia lati kú lẹ̃kanṣoṣo, ṣugbọn lẹhin eyi idajọ:

28 Bẹ̃ni Kristi pẹlu lẹhin ti a ti fi rubọ lẹ̃kanṣoṣo lati ru ẹ̀ṣẹ ọ̀pọlọpọ, yio farahan nigbakeji laisi ẹ̀ṣẹ fun awọn ti nwo ọna rẹ̀ fun igbala.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13