20 Nipa ọ̀na titun ati ãye, ti o yà si mimọ́ fun wa, ati lati kọja aṣọ ikele nì, eyini ni, ara rẹ̀;
21 Ati bi a ti ni alufa giga lori ile Ọlọrun;
22 Ẹ jẹ ki a fi otitọ ọkàn sunmọ tosi ni ẹ̀kún igbagbọ́, ki a si wẹ̀ ọkàn wa mọ́ kuro ninu ẹri-ọkàn buburu, ki a si fi omi mimọ́ wẹ̀ ara wa nù.
23 Ẹ jẹ ki a dì ijẹwọ ireti wa mu ṣinṣin li aiṣiyemeji; (nitoripe olõtọ li ẹniti o ṣe ileri;)
24 Ẹ jẹ ki a yẹ ara wa wo lati rú ara wa si ifẹ ati si iṣẹ rere:
25 Ki a má mã kọ ipejọpọ̀ ara wa silẹ, gẹgẹ bi àṣa awọn ẹlomiran; ṣugbọn ki a mã gbà ara ẹni niyanju: pẹlupẹlu bi ẹnyin ti ri pe ọjọ nì nsunmọ etile.
26 Nitori bi awa ba mọ̃mọ̀ dẹṣẹ lẹhin igbati awa ba ti gbà ìmọ otitọ kò tun si ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ mọ́,