35 Nitorina ẹ máṣe gbe igboiya nyin sọnu, eyiti o ni ère nla.
36 Nitori ẹnyin kò le ṣe alaini sũru, nitori igbati ẹnyin ba ti ṣe ifẹ Ọlọrun tan, ki ẹnyin ki o le gbà ileri na.
37 Nitori niwọn igba diẹ si i, Ẹni nã ti mbọ̀ yio de, kì yio si jafara.
38 Ṣugbọn olododo ni yio yè nipa igbagbọ́: ṣugbọn bi o ba fà sẹhin, ọkàn mi kò ni inu didùn si i.
39 Ṣugbọn awa kò si ninu awọn ti nfà sẹhin sinu egbé; bikoṣe ninu awọn ti o gbagbọ́ si igbala ọkàn.