31 Nipa igbagbọ́ ni Rahabu panṣaga kò ṣegbé pẹlu awọn ti kò gbọran, nigbati o tẹwọgbà awọn amí li alafia.
32 Ewo li emi o si tun mã wi si i? nitoripe ãyè kò ni tó fun mi lati sọ ti Gideoni, ati Baraku, ati Samsoni, ati Jefta; ti Dafidi, ati Samueli, ati ti awọn woli:
33 Awọn ẹni nipasẹ igbagbọ́ ti nwọn ṣẹgun ilẹ ọba, ti nwọn ṣiṣẹ ododo, ti nwọn gbà ileri, ti nwọn dí awọn kiniun li ẹnu,
34 Ti nwọn pa agbara iná, ti nwọn bọ́ lọwọ oju-idà, ti a sọ di alagbara ninu ailera, ti nwọn di akọni ni ìja, nwọn lé ogun awọn àjeji sá.
35 Awọn obinrin ri okú wọn gbà nipa ajinde: a si dá awọn ẹlomiran lóro, nwọn kọ̀ lati gbà ìdasilẹ; ki nwọn ki o le ri ajinde ti o dara jù gbà:
36 Awọn ẹlomiran si ri idanwò ti ẹsín, ati ti ìnà, ati ju bẹ̃ lọ ti ìde ati ti tubu:
37 A sọ wọn li okuta, a fi ayùn rẹ́ wọn meji, a dán wọn wò, a fi idà pa wọn: nwọn rìn kákiri ninu awọ agutan ati ninu awọ ewurẹ; nwọn di alaini, olupọnju, ẹniti a nda loro;