6 Ṣugbọn li aisi igbagbọ́ ko ṣe iṣe lati wù u; nitori ẹniti o ba ntọ̀ Ọlọrun wá kò le ṣai gbagbọ́ pe o mbẹ, ati pe on ni olusẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wá a.
7 Nipa igbagbọ́ ni Noa, nigbati Ọlọrun kilọ ohun ti koi ti iri fun u, o bẹru Ọlọrun, o si kàn ọkọ̀ fun igbala ile rẹ̀, nipa eyiti o dá aiye lẹbi, o si di ajogún ododo ti iṣe nipa igbagbọ́.
8 Nipa igbagbọ́ ni Abrahamu, nigbati a ti pè e lati jade lọ si ibi ti on yio gbà fun ilẹ-ini, o gbọ́, o si jade lọ, lai mọ̀ ibiti on nrè.
9 Nipa igbagbọ́ li o ṣe atipo ni ilẹ ileri, bi ẹnipe ni ilẹ àjeji, o ngbé inu agọ́, pẹlu Isaaki ati Jakọbu, awọn ajogún ileri kanna pẹlu rẹ̀:
10 Nitoriti o nreti ilu ti o ni ipilẹ̀; eyiti Ọlọrun tẹ̀do ti o si kọ́.
11 Nipa igbagbọ́ ni Sara tikararẹ̀ pẹlu fi ni agbara lati lóyun, nigbati o kọja ìgba rẹ̀, nitoriti o kà ẹniti o ṣe ileri si olõtọ.
12 Nitorina li ọ̀pọlọpọ ṣe ti ara ẹnikan jade, ani ara ẹniti o dabi okú, ọ̀pọ bi irawọ oju ọrun li ọ̀pọlọpọ, ati bi iyanrin eti okun li ainiye.