7 Nipa igbagbọ́ ni Noa, nigbati Ọlọrun kilọ ohun ti koi ti iri fun u, o bẹru Ọlọrun, o si kàn ọkọ̀ fun igbala ile rẹ̀, nipa eyiti o dá aiye lẹbi, o si di ajogún ododo ti iṣe nipa igbagbọ́.
8 Nipa igbagbọ́ ni Abrahamu, nigbati a ti pè e lati jade lọ si ibi ti on yio gbà fun ilẹ-ini, o gbọ́, o si jade lọ, lai mọ̀ ibiti on nrè.
9 Nipa igbagbọ́ li o ṣe atipo ni ilẹ ileri, bi ẹnipe ni ilẹ àjeji, o ngbé inu agọ́, pẹlu Isaaki ati Jakọbu, awọn ajogún ileri kanna pẹlu rẹ̀:
10 Nitoriti o nreti ilu ti o ni ipilẹ̀; eyiti Ọlọrun tẹ̀do ti o si kọ́.
11 Nipa igbagbọ́ ni Sara tikararẹ̀ pẹlu fi ni agbara lati lóyun, nigbati o kọja ìgba rẹ̀, nitoriti o kà ẹniti o ṣe ileri si olõtọ.
12 Nitorina li ọ̀pọlọpọ ṣe ti ara ẹnikan jade, ani ara ẹniti o dabi okú, ọ̀pọ bi irawọ oju ọrun li ọ̀pọlọpọ, ati bi iyanrin eti okun li ainiye.
13 Gbogbo awọn wọnyi li o kú ni igbagbọ́, lai ri ileri wọnni gbà, ṣugbọn ti nwọn ri wọn li òkere rere, ti nwọn si gbá wọn mú, ti nwọn si jẹwọ pe alejò ati atipò li awọn lori ilẹ aiye.