1 NITORINA o yẹ ti awa iba mã fi iyè gidigidi si ohun wọnni ti awa ti gbọ́, ki a má bã gbá wa lọ kuro ninu wọn nigbakan.
2 Nitori bi ọ̀rọ ti a ti ẹnu awọn angẹli sọ ba duro ṣinṣin, ati ti olukuluku irekọja ati aigbọran si gbà ẹsan ti o tọ́;
3 Awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nani irú igbala nla bi eyi; ti àtetekọ bẹ̀rẹ si isọ lati ọdọ Oluwa, ti a si fi mulẹ fun wa lati ọdọ awọn ẹniti o gbọ́;
4 Ọlọrun si nfi iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu, ati onirũru iṣẹ agbara, ati ẹ̀bun Ẹmí Mimọ́ bá wọn jẹri gẹgẹ bí ifẹ rẹ̀?
5 Nitoripe ki iṣe abẹ awọn angẹli li o fi aiye ti mbọ̀ ti awa nsọrọ rẹ̀ si.
6 Ṣugbọn ẹnikan sọ nibikan wipe, Kili enia ti o fi nṣe iranti rẹ̀, tabi ọmọ enia, ti o mbẹ̀ ẹ wò?
7 Iwọ dá a rẹlẹ̀ diẹ jù awọn angẹli lọ; iwọ fi ogo ati ọlá dé e li ade, iwọ si fi i jẹ olori iṣẹ ọwọ́ rẹ: