11 Bi mo ti bura ni ibinu mi, nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi.
12 Ẹ kiyesara, ará, ki ọkàn buburu ti aigbagbọ́ ki o máṣe wà ninu ẹnikẹni nyin, ni lilọ kuro lọdọ Ọlọrun alãye.
13 Ṣugbọn ẹ mã gbà ara nyin niyanju li ojojumọ́, niwọn igbati a ba npè e ni Oni, ki a má bã sé ọkàn ẹnikẹni ninu nyin le nipa ẹ̀tan ẹ̀ṣẹ.
14 Nitori awa di alabapín pẹlu Kristi, bi awa ba dì ipilẹṣẹ igbẹkẹle wa mu ṣinṣin titi de opin;
15 Nigbati a nwipe, Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn nyin le, bi igba imunibinu.
16 Nitori awọn tani bi nyin ninu nigbati nwọn gbọ́? Ki ha iṣe gbogbo awọn ti o ti ipasẹ Mose jade lati Egipti wá?
17 Awọn tali o si binu si fun ogoji ọdún? Ki ha iṣe si awọn ti o dẹṣẹ, okú awọn ti o sun li aginjù?