13 Ṣugbọn ẹ mã gbà ara nyin niyanju li ojojumọ́, niwọn igbati a ba npè e ni Oni, ki a má bã sé ọkàn ẹnikẹni ninu nyin le nipa ẹ̀tan ẹ̀ṣẹ.
14 Nitori awa di alabapín pẹlu Kristi, bi awa ba dì ipilẹṣẹ igbẹkẹle wa mu ṣinṣin titi de opin;
15 Nigbati a nwipe, Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn nyin le, bi igba imunibinu.
16 Nitori awọn tani bi nyin ninu nigbati nwọn gbọ́? Ki ha iṣe gbogbo awọn ti o ti ipasẹ Mose jade lati Egipti wá?
17 Awọn tali o si binu si fun ogoji ọdún? Ki ha iṣe si awọn ti o dẹṣẹ, okú awọn ti o sun li aginjù?
18 Awọn tali o si bura fun pe nwọn kì yio wọ̀ inu isimi on, bikoṣe fun awọn ti kò gbọran?
19 Awa si ri pe nwọn kò le wọ̀ inu rẹ̀ nitori aigbagbọ́.