7 Ẹni nigba ọjọ rẹ̀ ninu ara, ti o fi ẹkún rara ati omije gbadura, ti o si bẹ̀bẹ lọdọ ẹniti o le gbà a silẹ lọwọ ikú, a si gbohun rẹ̀ nitori ẹmi ọ̀wọ rẹ̀,
8 Bi o ti jẹ Ọmọ nì, sibẹ o kọ́ igbọran nipa ohun ti o jìya;
9 Bi a si ti sọ ọ di pipé, o wá di orisun igbala ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o ngbọ́ tirẹ̀:
10 Ti a yàn li Olori Alufa lati ọdọ Ọlọrun wá nipa ẹsẹ Melkisedeki.
11 Niti ẹniti awa ni ohun pupọ̀ lati sọ, ti o si ṣoro lati tumọ, nitoripe ẹ yigbì ni gbigbọ́.
12 Nitori nigbati akokò tó ti o yẹ ki ẹ jẹ olukọ, ẹ tun wà ni ẹniti ẹnikan yio mã kọ́ ni ibẹrẹ ipilẹ awọn ọ̀rọ Ọlọrun; ẹ si di irú awọn ti kò le ṣe aini wàra, ti nwọn kò si fẹ onjẹ lile.
13 Nitori olukuluku ẹniti nmu wàra jẹ́ alailoye ọ̀rọ ododo: nitori ọmọ-ọwọ ni.