5 Ati lori rẹ̀ ni awọn kerubu ogo ti o ṣijibo ìtẹ́ ãnu; eyiti a kò le sọrọ rẹ̀ nisisiyi lọkọ̃kan.
6 Njẹ nigbati a ti ṣe ètò nkan wọnyi bayi, awọn alufa a mã lọ nigbakugba sinu agọ́ ekini, nwọn a mã ṣe iṣẹ ìsin.
7 Ṣugbọn sinu ekeji ni olori alufa nikan imã lọ lẹ̃kanṣoṣo li ọdún, kì iṣe li aisi ẹ̀jẹ, ti on fi rubọ fun ara rẹ̀ na, ati fun ìṣina awọn enia:
8 Ẹmí Mimọ́ ntọka eyi pé a kò ti iṣi ọ̀na ibi mimọ́ silẹ niwọn igbati agọ́ ekini ba duro.
9 Eyiti iṣe apẹrẹ fun igba isisiyi gẹgẹ bi eyiti a nmu ẹ̀bun ati ẹbọ wá, ti kò le mu olusin di pipé niti ohun ti ẹri-ọkàn,
10 Eyiti o wà ninu ohun jijẹ ati ohun mimu ati onirũru ìwẹ, ti iṣe ìlana ti ara nikan ti a fi lelẹ titi fi di igba atunṣe.
11 Ṣugbọn nigbati Kristi de bi Olori Alufa awọn ohun rere ti mbọ̀, nipaṣe agọ́ ti o tobi ti o si pé ju ti iṣaju, eyiti a kò fi ọwọ́ pa, eyini ni, ti kì iṣe ti ẹ̀da yi.