1 PAULU, ati Silfanu, ati Timotiu, si ijọ awọn ara Tessalonika, ninu Ọlọrun Baba, ati ninu Jesu Kristi Oluwa: Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.
2 Awa ndupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo fun gbogbo nyin, awa nṣe iranti nyin ninu adura wa;
3 Li aisimi li awa nranti iṣẹ igbagbọ́ nyin ati lãla ifẹ ati sũru ireti nyin ninu Oluwa wa Jesu Kristi, niwaju Ọlọrun ati Baba wa;
4 Nitoripe awa mọ yiyan nyin, ara olufẹ ti Ọlọrun,
5 Bi ihinrere wa kò ti wá sọdọ nyin li ọ̀rọ nikan, ṣugbọn li agbara pẹlu, ati ninu Ẹmí Mimọ́, ati ni ọ̀pọlọpọ igbẹkẹle; bi ẹnyin ti mọ̀ irú enia ti awa jẹ́ larin nyin nitori nyin.