1. Tes 5 YCE

Ẹ Múra Sílẹ̀ De Ìpadàbọ̀ Oluwa

1 ṢUGBỌN niti akokò ati ìgba wọnni, ará, ẹnyin kò tun fẹ ki a kọ ohunkohun si nyin,

2 Nitoripe ẹnyin tikaranyin mọ̀ dajudaju pe, ọjọ Oluwa mbọ̀wá gẹgẹ bi olè li oru.

3 Nigbati nwọn ba nwipe, alafia ati ailewu; nigbana ni iparun ojijì yio de sori wọn gẹgẹ bi irọbi lori obinrin ti o lóyun; nwọn kì yio si le sálà.

4 Ṣugbọn ẹnyin, ará, kò si ninu òkunkun, ti ọjọ na yio fi de bá nyin bi olè.

5 Nitori gbogbo nyin ni ọmọ imọlẹ, ati ọmọ ọsán: awa kì iṣe ti oru, tabi ti òkunkun.

6 Nitorina ẹ máṣe jẹ ki a sùn, bi awọn iyoku ti nṣe; ṣugbọn ẹ jẹ ki a mã ṣọna ki a si mã wa ni airekọja.

7 Nitori awọn ti nsùn, ama sùn li oru; ati awọn ti nmutipara, ama mutipara li oru.

8 Ṣugbọn ẹ jẹ ki awa, bi a ti jẹ ti ọsán, mã wà li airekọja, ki a mã gbé igbaiya igbagbọ́ ati ifẹ wọ̀; ati ireti igbala fun aṣibori.

9 Nitori Ọlọrun yàn wa ki iṣe si ibinu, ṣugbọn si ati ni igbala nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa,

10 Ẹniti o kú fun wa, pe bi a ba jí, tabi bi a ba sùn, ki a le jùmọ wà lãye pẹlu rẹ̀.

11 Nitorina ẹ mã gbà ara nyin niyanju, ki ẹ si mã fi ẹsẹ ara nyin mulẹ, ani gẹgẹ bi ẹnyin ti nṣe.

Gbolohun Ìparí

12 Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, lati mã mọ awọn ti nṣe lãla larin nyin, ti nwọn si nṣe olori nyin ninu Oluwa, ti nwọn si nkìlọ fun nyin;

13 Ki ẹ si mã bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ nitori iṣẹ wọn. Ẹ si mã wà li alafia lãrin ara nyin.

14 Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, ki ẹ mã kìlọ fun awọn ti iṣe alaigbọran, ẹ mã tù awọn alailọkàn ninu, ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ẹ mã mu sũru fun gbogbo enia.

15 Ẹ kiyesi i, ki ẹnikẹni ki o máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni; ṣugbọn ẹ mã lepa eyi ti iṣe rere nigbagbogbo, lãrin ara nyin, ati larin gbogbo enia.

16 Ẹ mã yọ̀ nigbagbogbo.

17 Ẹ mã gbadura li aisimi.

18 Ẹ mã dupẹ ninu ohun gbogbo: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu fun nyin.

19 Ẹ máṣe pa iná Ẹmí.

20 Ẹ máṣe kẹgan isọtẹlẹ.

21 Ẹ mã wadi ohun gbogbo daju; ẹ dì eyiti o dara mu ṣinṣin.

22 Ẹ mã takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi.

23 Ki Ọlọrun alafia tikararẹ̀ ki o sọ nyin di mimọ́ patapata; ki a si pa ẹmí ati ọkàn ati ara nyin mọ́ patapata li ailabukù ni ìgba wíwa Oluwa wa Jesu Kristi.

24 Olododo li ẹniti o pè nyin, ti yio si ṣe e.

25 Ará, ẹ mã gbadura fun wa.

26 Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí gbogbo awọn ará.

27 Mo fi Oluwa mu nyin bura pe, ki a ka iwe yi fun gbogbo awọn ará.

28 Ki ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi ki o wà pẹlu nyin. Amin.

orí

1 2 3 4 5