1. Tes 4 YCE

Ìgbé-Ayé Tí Ó Wu Ọlọrun

1 NJẸ li akotan, ará, awa mbẹ̀ nyin, awa si ngbà nyin niyanju ninu Jesu Oluwa, pe bi ẹnyin ti gbà lọwọ wa bi ẹnyin iba ti mã rìn, ti ẹnyin iba si mã wù Ọlọrun, ani gẹgẹ bi ẹnyin ti nrìn, ki ẹnyin le mã pọ̀ siwaju si i.

2 Nitori ẹnyin mọ̀ irú aṣẹ ti a ti pa fun nyin lati ọdọ Jesu Oluwa.

3 Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimọ́ nyin, pe ki ẹnyin ki o takéte si àgbere:

4 Ki olukuluku nyin le mọ̀ bi on iba ti mã ko ohun èlo rẹ̀ ni ijanu ni ìwa-mimọ́ ati ni ọlá;

5 Kì iṣe ni ṣiṣe ifẹkufẹ, gẹgẹ bi awọn Keferi ti kò mọ̀ Ọlọrun:

6 Ki ẹnikẹni máṣe rekọja, ki o má si ṣe ṣẹ arakunrin rẹ̀ ninu nkan na: nitori Oluwa ni olugbẹsan ninu gbogbo nkan wọnyi, gẹgẹ bi awa ti kilọ fun nyin tẹlẹ, ti a si jẹri pẹlu.

7 Nitori Ọlọrun kò pè wa fun ìwa ẽri, ṣugbọn ni ìwamimọ́.

8 Nitorina ẹnikẹni ti o bá kọ̀, ko kọ̀ enia, bikoṣe Ọlọrun, ẹniti o fun nyin ni Ẹmí Mimọ́ rẹ̀ pẹlu.

9 Ṣugbọn niti ifẹ awọn ará, ẹ kò tun fẹ ki ẹnikẹni kọwe si nyin: nitori a ti kọ́ ẹnyin tikaranyin lati ọdọ Ọlọrun wá lati mã fẹ ara nyin.

10 Nitõtọ ẹnyin si nṣe e si gbogbo awọn ará ti o wà ni gbogbo Makedonia: ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, pe ki ẹnyin ki o mã pọ̀ siwaju si i;

11 Ati pe ki ẹnyin ki o mã dù u gidigidi lati gbé jẹ, lati mã gbọ ti ara nyin, ki ẹ mã fi ọwọ́ nyin ṣiṣẹ, gẹgẹ bi awa ti paṣẹ fun nyin;

12 Ki ẹnyin ki o le mã rìn ìrin ẹ̀tọ́ si awọn ti mbẹ lode, ki ẹ le má ṣe alaini ohunkohun.

Àkókò Tí Oluwa Yóo Dé

13 Ṣugbọn awa kò fẹ ki ẹnyin ki o jẹ òpe, ará, niti awọn ti o sùn, pe ki ẹ má binujẹ gẹgẹ bi awọn iyoku ti kò ni ireti.

14 Nitori bi awa ba gbagbọ́ pe Jesu ti kú, o si ti jinde, gẹgẹ bẹ̃ni Ọlọrun yio mu awọn ti o sùn pẹlu ninu Jesu wá pẹlu ara rẹ̀.

15 Nitori eyiyi li awa nwi fun nyin nipa ọ̀rọ Oluwa, pe awa ti o wà lãye, ti a si kù lẹhin de atiwá Oluwa, bi o ti wu ki o ri kì yio ṣaju awọn ti o sùn.

16 Nitori Oluwa tikararẹ̀ yio sọkalẹ lati ọrun wá ti on ti ariwo, pẹlu ohùn olori awọn angẹli, ati pẹlu ipè Ọlọrun; awọn okú ninu Kristi ni yio si kọ́ jinde:

17 Nigbana li a ó si gbà awa ti o wà lãye ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun: bẹ̃li awa ó si ma wà titi lai lọdọ Oluwa.

18 Nitorina, ẹ mã fi ọ̀rọ wọnyi tu ara nyin ninu.

orí

1 2 3 4 5