4 Nitori nitõtọ nigbati awa wà lọdọ nyin, a ti nsọ fun nyin tẹlẹ pe, awa ó ri wahalà; gẹgẹ bi o si ti ṣẹ, ti ẹnyin si mọ̀.
5 Nitori eyi, nigbati ara mi kò gba a mọ́, mo si ranṣẹ ki emi ki o le mọ igbagbọ́ nyin ki oludanwò nì má bã ti dan nyin wo lọnakọna, ki lãlã wa si jẹ asan.
6 Ṣugbọn nisisiyi ti Timotiu ti ti ọdọ nyin wá sọdọ wa, ti o si ti mu ihinrere ti igbagbọ́ ati ifẹ nyin wá fun wa, ati pe ẹnyin nṣe iranti wa ni rere nigbagbogbo, ẹnyin si nfẹ gidigidi lati ri wa, bi awa pẹlu si ti nfẹ lati ri nyin:
7 Nitori eyi, ará, awa ni itunu lori nyin ninu gbogbo wahalà ati ipọnju wa nitori igbagbọ́ nyin:
8 Nitori awa yè nisisiyi, bi ẹnyin ba duro ṣinṣin ninu Oluwa.
9 Nitori ọpẹ́ kili awa le tún ma dá lọwọ Ọlọrun nitori nyin, fun gbogbo ayọ̀ ti awa nyọ̀ nitori nyin niwaju Ọlọrun wa;
10 Li ọsán ati li oru li awa ngbadura gidigidi pe, ki awa ki o le ri oju nyin, ki a si ṣe aṣepé eyiti o kù ninu igbagbọ́ nyin?