1 PAULU, Aposteli Kristi Jesu, gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Olugbala wa, ati Kristi Jesu ireti wa;
2 Si Timotiu, ọmọ mi tõtọ ninu igbagbọ́: Ore-ọfẹ, ãnu, alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Kristi Jesu Oluwa wa.
3 Bi mo ti gba ọ niyanju lati joko ni Efesu, nigbati mo nlọ si Makedonia, ki iwọ ki o le paṣẹ fun awọn kan, ki nwọn ki o máṣe kọ́ni li ẹkọ́ miran,
4 Ki nwọn má si ṣe fiyesi awọn itan lasan, ati ti ìran ti kò li opin, eyiti imã mú ijiyan wa dipo iṣẹ iriju Ọlọrun ti mbẹ ninu igbagbọ́; bẹni mo ṣe nisisiyi.
5 Ṣugbọn opin aṣẹ na ni ifẹ lati ọkàn mimọ́ ati ẹri-ọkan rere ati igbagbọ́ aiṣẹtan wa.