1. Tim 3 YCE

Irú Ẹni Tí Olùdarí Ìjọ Ní láti Jẹ́

1 OTITỌ ni ọ̀rọ na, bi ẹnikan ba fẹ oyè biṣopu, iṣẹ rere li o nfẹ.

2 Njẹ biṣopu jẹ alailẹgan, ọkọ aya kan, oluṣọra, alairekọja, oniwa yiyẹ, olufẹ alejò ṣiṣe, ẹniti o le ṣe olukọ.

3 Ki o má jẹ ọmuti, tabi onijà, tabi olojukokoro, bikoṣe onisũru, ki o má jẹ onija, tabi olufẹ owo;

4 Ẹniti o kawọ ile ara rẹ̀ girigiri, ti o mu awọn ọmọ rẹ̀ tẹriba pẹlu ìwa àgba gbogbo;

5 (Ṣugbọn bi enia kò ba mọ̀ bi ã ti ṣe ikawọ ile ara rẹ̀, on o ha ti ṣe le tọju ijọ Ọlọrun?)

6 Ki o má jẹ ẹni titun, kí o má bã gbéraga, ki o si ṣubu sinu ẹbi Èṣu.

7 O si yẹ kí o ni ẹri rere pẹlu lọdọ awọn ti mbẹ lode: kí o má ba bọ sinu ẹ̀gan ati sinu idẹkun Èṣu.

Irú Ẹni Tí Diakoni Ní láti Jẹ́

8 Bẹ̃ gẹgẹ li o yẹ fun awọn diakoni lati ni ìwa àgba, ki nwọn má jẹ ẹlẹnu meji, kì nwọn má fi ara wọn fun waini pupọ̀, ki nwọn má jẹ olojukokoro.

9 Ki nwọn mã di ohun ijinlẹ igbagbọ́ mu li ọkàn funfun.

10 Ki a si kọ́ wá idi awọn wọnyi daju pẹlu; nigbana ni ki a jẹ ki nwọn jẹ oyè diakoni, bi nwọn ba jẹ alailẹgan.

11 Bẹ̃ gẹgẹ li o yẹ fun awọn obinrin lati ni iwa àgba, kì nwọn má jẹ asọrọ-ẹni-lẹhin bikoṣe alairekọja, olõtọ li ohun gbogbo.

12 Ki awọn diakoni jẹ ọkọ obinrin kan, ki nwọn ki o káwọ awọn ọmọ wọn ati ile ara wọn daradara.

13 Nitori awọn ti o lò oyè diakoni daradara rà ipo rere fun ara wọn, ati igboiya pupọ ni igbagbọ́ ti mbẹ ninu Kristi Jesu.

Ohun Ìjìnlẹ̀ Ẹ̀sìn Wa

14 Iwe nkan wọnyi ni mo kọ si ọ, mo si nreti ati tọ̀ ọ wá ni lọ̃lọ̃.

15 Ṣugbọn bi mo ba pẹ, ki iwọ ki o le mọ̀ bi o ti yẹ fun awọn enia lati mã huwa ninu ile Ọlọrun, ti iṣe ijọ Ọlọrun alãye, ọwọ̀n ati ipilẹ otitọ.

16 Laiṣiyemeji, titobi ni ohun ijinlẹ ìwa-bi-Ọlọrun, ẹniti a fihan ninu ara, ti a dalare ninu Ẹmí, ti awọn angẹli ri, ti a wasu rẹ̀ lãrin awọn orilẹ-ede, ti a gbagbọ ninu aiye, ti a gba soke sinu ogo.

orí

1 2 3 4 5 6