1. Tim 5 YCE

Iṣẹ́ sí Àwọn tí ó Gbàgbọ́

1 MÁṢE ba alàgba wi, ṣugbọn ki o mã gba a niyanju bi baba; awọn ọdọmọkunrin bi arakunrin;

2 Awọn àgba obinrin bi iya; awọn ọdọmọbirin bi arabinrin ninu ìwa mimọ́.

3 Bọ̀wọ fun awọn opó ti iṣe opó nitõtọ.

4 Ṣugbọn bi opó kan ba li ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, jẹ ki nwọn tète kọ́ ati ṣe itọju ile awọn tikarawọn, ki nwọn ki o si san õre awọn obi wọn pada: nitoripe eyi li o ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun.

5 Njẹ ẹniti iṣe opó nitõtọ, ti o ṣe on nikan, a mã gbẹkẹle Ọlọrun, a si mã duro ninu ẹ̀bẹ ati ninu adura lọsán ati loru.

6 Ṣugbọn ẹniti o ba fi ara rẹ̀ fun aiye jijẹ, o kú nigbati o wà lãye.

7 Nkan wọnyi ni ki iwọ ki o si mã palaṣẹ, ki nwọn ki o le wà lailẹgan.

8 Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò bá pèse fun awọn tirẹ, papa fun awọn ará ile rẹ̀, o ti sẹ́ igbagbọ́, o buru ju alaigbagbọ́ lọ.

9 Máṣe kọ orukọ ẹniti o ba din ni ọgọta ọdún silẹ bi opó, ti o ti jẹ obinrin ọkọ kan,

10 Ẹniti a jẹri rẹ̀ fun iṣẹ rere; bi o ba ti ntọ́ ọmọ ri, bi o ba ti ngba alejò, bi o bá ti nwẹ ẹsẹ awọn enia mimọ́, bi o ba ti nràn awọn olupọnju lọwọ, bi o ba ti nlepa iṣẹ rere gbogbo.

11 Ṣugbọn kọ̀ awọn opo ti kò dagba: nitoripe nigbati nwọn ba ti ṣe ifẹkufẹ lodi si Kristi, nwọn a fẹ gbeyawo;

12 Nwọn a di ẹlẹbi, nitoriti nwọn ti kọ̀ igbagbọ́ wọn iṣaju silẹ.

13 Ati pẹlu nwọn nkọ́ lati ṣe ọlẹ, lati mã kiri lati ile de ile; ki iṣe ọlẹ nikan, ṣugbọn onisọkusọ ati olofòfo pẹlu, nwọn a ma sọ ohun ti kò yẹ.

14 Nitorina mo fẹ ki awọn opo ti kò dagba mã gbeyawo, ki nwọn mã bímọ, ki nwọn ki o mã ṣe alabojuto ile, ki nwọn ki o máṣe fi àye silẹ rara fun ọtá na lati sọ̀rọ ẹ̀gan.

15 Nitori awọn miran ti yipada kuro si ẹhin Satani.

16 Bi obinrin kan ti o gbagbọ́ ba ni awọn opó, ki o mã ràn wọn lọwọ, ki a má si di ẹrù le ijọ, ki nwọn ki o le mã ràn awọn ti iṣe opó nitõtọ lọwọ.

17 Awọn alàgba ti o ṣe akoso daradara ni ki a kà yẹ si ọlá ilọpo meji, pẹlupẹlu awọn ti o ṣe lãlã ni ọ̀rọ ati ni kikọni.

18 Nitoriti iwe-mimọ́ wipe, Iwọ kò gbọdọ dì malu ti ntẹ̀ ọkà li ẹnu. Ati pe, ọ̀ya alagbaṣe tọ si i.

19 Máṣe gbà ẹ̀sun si alàgba kan, bikoṣe lati ẹnu ẹlẹri meji tabi mẹta.

20 Ba awọn ti o ṣẹ̀ wi niwaju gbogbo enia, ki awọn iyokù pẹlu ki o le bẹ̀ru.

21 Mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kristi Jesu, ati awọn angẹli ayanfẹ, ki iwọ ki o mã ṣakiyesi nkan wọnyi, laiṣe ojuṣãju, lai fi ègbè ṣe ohunkohun.

22 Máṣe fi ikanju gbe ọwọ́ le ẹnikẹni, bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ alabapin ninu ẹ̀ṣẹ̀ awọn ẹlomiran: pa ara rẹ mọ́ ni ìwa funfun.

23 Máṣe mã mu omi nikan, ṣugbọn mã lo waini diẹ nitori inu rẹ, ati nitori ailera rẹ igbakugba.

24 Ẹ̀ṣẹ awọn ẹlomiran a mã han gbangba, a mã lọ ṣãju si idajọ; ti awọn ẹlomiran pẹlu a si mã tẹle wọn.

25 Bẹ̃ gẹgẹ pẹlu ni iṣẹ rere wà ti nwọn hàn gbangba; awọn iru miran kò si le farasin.

orí

1 2 3 4 5 6