17 Njẹ fun Ọba aiyeraiye, aidibajẹ, airi, Ọlọrun kanṣoṣo, ni ọlá ati ogo wà fun lai ati lailai. Amin.
18 Aṣẹ yi ni mo pa fun ọ, Timotiu ọmọ mi, gẹgẹ bi isọtẹlẹ wọnni ti o ti ṣaju lori rẹ, pe nipa wọn ki iwọ ki o le mã jà ogun rere;
19 Mã ni igbagbọ́ ati ẹri-ọkàn rere; eyiti awọn ẹlomiran tanu kuro lọdọ wọn ti nwọn si rì ọkọ̀ igbagbọ́ wọn:
20 Ninu awọn ẹniti Himeneu ati Aleksanderu wà; awọn ti mo ti fi le Satani lọwọ, ki a le kọ́ wọn ki nwọn ki o má sọrọ-odi mọ́.