1 PAULU, ati Silfanu, ati Timotiu, si ijọ Tessalonika, ninu Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kristi Oluwa:
2 Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba, ati Jesu Kristi Oluwa.
3 Iṣẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, ani gẹgẹ bi o ti yẹ, nitoripe igbagbọ́ nyin ndàgba gidigidi, ati ifẹ olukuluku nyin gbogbo si ara nyin ndi pupọ;
4 Tobẹ̃ ti awa tikarawa nfi nyin ṣogo ninu ijọ Ọlọrun, nitori sũru ati igbagbọ́ nyin ninu gbogbo inunibini ati wahalà nyin ti ẹnyin nfarada,
5 Eyiti iṣe àmi idajọ ododo Ọlọrun ti o daju, ki a le kà nyin yẹ fun ijọba Ọlọrun, nitori eyiti ẹnyin pẹlu ṣe njìya:
6 Bi o ti jẹ pe ohun ododo ni fun Ọlọrun lati fi ipọnju gbẹsan lara awọn ti npọ́n nyin loju,
7 Ati fun ẹnyin, ti a npọ́n loju, isimi pẹlu wa, nigba ifarahàn Jesu Oluwa lati ọrun wá ninu ọwọ́ ina pẹlu awọn angẹli alagbara rẹ̀,