10 Nitori nigbati awa tilẹ wà pẹlu nyin, eyi li awa palaṣẹ fun nyin, pe bi ẹnikẹni kò bá fẹ ṣiṣẹ, ki o maṣe jẹun.
11 Nitori awa gburo awọn kan ti nrin ségesège larin nyìn ti nwọn kò nṣiṣẹ rara, ṣugbọn nwọn jẹ àtọjú-ile-kiri.
12 Njẹ irú awọn ẹni bẹ̃ li awa npaṣẹ fun, ti a si nrọ̀ ninu Oluwa Jesu Kristi, pe ki nwọn ki o mã fi ìwa pẹlẹ ṣiṣẹ, ki nwọn ki o si mã jẹ onjẹ awọn tikarawọn.
13 Ṣugbọn ẹnyin, ará, ẹ máṣe ṣãrẹ̀ ni rere iṣe.
14 Bi ẹnikẹni kò ba si gbà ọ̀rọ wa gbọ́ nipa iwe yi, ẹ sami si oluwarẹ, ki ẹ má si ṣe ba a kẹgbẹ, ki oju ki o le tì i.
15 Sibẹ ẹ máṣe kà a si ọtá, ṣugbọn ẹ mã gbà a niyanju bi arakunrin.
16 Njẹ ki Oluwa alafia tikararẹ̀ mã fun nyin ni alafia nigbagbogbo lọna gbogbo. Ki Oluwa ki o pẹlu gbogbo nyin.