17 Ṣugbọn Oluwa gbà ẹjọ mi ro, o si fun mi lagbara; pe nipasẹ mi ki a le wãsu na ni awàjálẹ̀, ati pe ki gbogbo awọn Keferi ki o le gbọ́: a si gbà mi kuro li ẹnu kiniun nì.
18 Oluwa yio yọ mi kuro ninu iṣẹ buburu gbogbo, yio si gbé mi de inu ijọba rẹ̀ ọrun: ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin.
19 Kí Priskilla ati Akuila, ati ile Onesiforu.
20 Erastu wà ni Korinti: ṣugbọn mo fi Trofimu silẹ ni Miletu ninu aisan.
21 Sa ipa rẹ lati tete wá ṣaju ìgba otutù. Eubulu kí ọ, ati Pudeni, ati Linu, ati Klaudia, ati gbogbo awọn arakunrin.
22 Ki Oluwa ki o wà pẹlu ẹmí rẹ. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu nyin. Amin.