9 Pẹlu Onesimu, arakunrin olõtọ ati olufẹ, ẹniti iṣe ọ̀kan ninu nyin. Awọn ni yio sọ ohun gbogbo ti a nṣe nihinyi fun nyin.
10 Aristarku, ẹlẹgbẹ mi ninu tubu ki nyin, ati Marku, ọmọ arabinrin Barnaba (nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbà aṣẹ: bi o ba si wá sọdọ nyin, ẹ gbà a),
11 Ati Jesu, ẹniti a npè ni Justu, ẹniti iṣe ti awọn onila. Awọn wọnyi nikan ni olubaṣiṣẹ mi fun ijọba Ọlọrun, awọn ẹniti o ti jasi itunu fun mi.
12 Epafra, ẹniti iṣe ọkan ninu nyin, iranṣẹ Kristi, kí nyin, on nfi iwaya-ija gbadura nigbagbogbo fun nyin, ki ẹnyin ki o le duro ni pipé ati ni kíkun ninu gbogbo ifẹ Ọlọrun.
13 Nitori mo jẹri rẹ̀ pe, o ni itara pupọ fun nyin, ati fun awọn ti o wà ni Laodikea, ati awọn ti o wà ni Hierapoli.
14 Luku, oniṣegun olufẹ, ati Dema ki nyin.
15 Ẹ kí awọn ará ti o wà ni Laodikea, ati Nimfa, ati ijọ ti o wà ni ile rẹ̀.