6 Ti o dà si wa lori lọpọlọpọ nipasẹ Jesu Kristi Olugbala wa;
7 Ki a le dá wa lare nipa ore-ọfẹ rẹ̀, ki a si le sọ wa di ajogún gẹgẹ bi ireti ìye ainipẹkun.
8 Otitọ li ọ̀rọ na, emi si nfẹ ki iwọ ki o tẹnumọ nkan wọnyi gidigidi, ki awọn ti o gbà Ọlọrun gbọ́ le mã tọju ati ṣe iṣẹ rere. Nkan wọnyi dara, nwọn si ṣe anfani fun enia.
9 Ṣugbọn yà kuro ni ìbẽre wère, ati ìtan iran, ati ijiyan, ati ija nipa ti ofin; nitoripe alailere ati asan ni nwọn.
10 Ẹniti o ba ṣe aladamọ̀ lẹhin ìkilọ ikini ati ekeji, kọ̀ ọ;
11 Ki o mọ̀ pe irú ẹni bẹ̃ ti yapa, o si ṣẹ̀, o dá ara rẹ̀ lẹbi.
12 Nigbati mo ba rán Artema si ọ, tabi Tikiku, yara tọ̀ mi wá ni Nikopoli: nitori ibẹ ni mo ti pinnu lati lo akoko otutu.