Ẹkún Jeremáyà 1:7-13 BMY

7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ niJérúsálẹ́mù rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá,kò sì sí olùrànlọ́wọ́ fún un.Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ówọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà.

8 Jérúsálẹ́mù sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ó sì ti di aláìmọ́.Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀,nítorí wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀;ó kérora fúnra rẹ̀,ó sì lọ kúrò.

9 Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀,Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu;olùtùnú kò sì sí fún un.“Wo ìpọ́njú mi, Olúwa,nítorí àwọn ọ̀ta ti borí.”

10 Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ légbogbo ìní rẹ;o rí àwọn ìlú abọ̀rìṣàtí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ—àwọn tí o ti kọ̀ sílẹ̀láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.

11 Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérorabí wọ́n ti ń wá oúnjẹ;wọ́n fi ohun ìní wọn se pàsípààrọ̀ oúńjẹláti mú wọn wà láàyè.“Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó,nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”

12 “Kò ha jẹ́ nǹkankan sí i yín?Gbogbo ẹ̀yin tí ń ré kọjá,Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyàtí a fi fún mi, ti Olúwa mú wá fún miní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.

13 “Ó rán iná láti òkèsọ̀kalẹ̀ sínú egungun ara mi.Ó dẹ àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi,ó sì yí mi padà.Ó ti pa mí láramó ń kú lọ ní gbogbo ọjọ́.